Eeyan marun-un ku sinu ijamba ọkọ oju omi n’Ilajẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan marun-un ni wọn padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ oju omi to waye lagbegbe kan ti wọn n pe ni Ugbo-Nla, nijọba ibilẹ Ilajẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.

ALAROYE gbọ pe awọn eeyan maraarun ọhun ni wọn pade iku airotẹlẹ pẹlu bi ọkọ oju omi tí wọn wa ninu rẹ ṣe dojude lojiji lasiko ti wọn wa laarin alagbalugbu omi.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin, Alaga ẹgbẹ awọn apẹja nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Orioye Benedict Gbayiṣemore, ni awọn ero mẹfa lọkọ oju omi ta a n sọrọ rẹ yii ko.

O ni awọn oúnjẹ inu omi ni wọn fẹẹ lọọ ra niluu Ugbo-Nla, ko too di pe ijamba ọkọ naa ko fun wọn laaye lati de ibi ti wọn n lọ.

Marun-un ninu awọn ero ọhun lo ni wọn ri sinu omi, ti wọn si gba ibẹ ku lẹyin ti ọkọ wọn dojude lori omi, ẹni kan ṣoṣo lo ni ori ko yọ ninu wọn latari ẹwu amu-ni-le-tente lori omi to wọ sọrun, eyi to mu ko wa lori omi, ti ko

si ri sisalẹ titi ti awọn to waa doola awọn ero naa fi de.

Ọkunrin naa waa rọ ijọba lati sọ ọ di dandan fun gbogbo awọn to ba ti n wọkọ oju omi ki wọn maa ṣamulo ẹwu amu-ni-le-tente yii nígbàkúùgbà ti wọn ba ti wa lori omi nitori aabo ẹ̀mí wọn.

 

Leave a Reply