Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Pẹlu bi ija agba ṣe n waye lemọlemọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun oriṣiiriṣii kaakiri ipinlẹ Ogun, ti wọn si n pa ara wọn, Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ yii, Edward Awolọwọ Ajogun, ti sọ pe ko din leeyan mẹẹẹdọgbọn (25) to ti padanu ẹmi wọn ninu awọn ija agba ọhun.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejila, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021, ni Ajogun sọrọ yii ni Kọmanmdi ọlọpaa to wa ni Igbẹba, n’Ijẹbu-Ode, lasiko to ba awọn olori agbegbe, awọn ọdọ atawọn alẹnulọrọ lori ohun to n ṣẹlẹ naa pade, to si tun foju awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mọkanla han fawọn akọroyin.
Ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii, Ijẹbu-Ode ko sinmi lọwọ awọn ọmọkunrin ti wọn n ṣe ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ, Aiye ati Aake Dudu, pẹlu bi wọn ṣe n ko idaamu ba awọn araalu ti ọrọ ko kan lasiko ti wọn ba bẹrẹ wahala wọn.
Kọmiṣanna sọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹrindinlogun lọwọ awọn ti ba laarin oṣu kan si asiko yii, bẹẹ ni ọpọlọpọ nnkan ija pẹlu oogun abẹnugọngọ lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn.
O fi kun un pe lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun to kọja, ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa padanu ẹmi ẹ lasiko tawọn ọlọpaa koju wọn.
Bo ṣe waa jẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Aiye, Aake Dudu ati Ẹiye ko fẹẹ gba alaafia laaye yii, Ajogun ni awọn agbofinro naa ko ni i pada lẹyin wọn nipinlẹ Ogun yii. O lawọn yoo maa wa wọn jade nibi yoowu ki wọn sa gba ni, wọn yoo si maa jiya to yẹ wọn labẹ ofin.
Lọjọ kẹsan-an, oṣu kin-in-ni yii, ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aake Dudu (Black Axe), Micheal Jayeọla, padanu ẹmi ẹ nigba ti wọn yinbọn pa a, bẹẹ ni wọn tun ge apa rẹ paapaa lọja Ijẹbu-Imushin. CP Ajogun lo fidi eyi mulẹ, bẹẹ lo ni bawọn ọlọpaa yoo ṣe maa ṣigun lọọ ba awọn ọmọ to n da alaafia Ijẹbu-Ode ati ipinlẹ Ogun lapapọ ru naa ni yii.
Ọga ọlọpaa yii ko ṣai de awọn orita ti wọn ni ibẹ lawọn ọmọ Aiye, Ẹiye ati Aake Dudu fi n ṣe ibuba n’Ijẹbu-Ode. O kilọ fawọn ọdọ ibẹ pe ki wọn jawọ bi wọn ko ba fẹẹ bọ sọwọ ofin, bẹẹ lo kilọ fawọn obi paapaa pe ki wọn fa awọn ọmọ wọn leti, kawọn olori adugbo naa ba awọn eeyan wọn sọrọ, nitori ẹni tọwọ ba tẹ pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, tọhun ko ni i le royin tan nigba tọwọ ọlọpaa ba tẹ ẹ. Awọn mi-in ti wa ni kootu ninu wọn ti wọn n jẹjọ apaayan ati iṣeeṣipaniyan gẹgẹ bi Ajogun ṣe wi.