Eeyan mẹẹẹdogun lo ku si ileeṣẹ ti wọn ti n sun taya kan to wa ni ikorita to lọ si Ilaro, niluu Papalanto, nijọba ibilẹ Ewekoro ti wọn n pe ni Burning Pyle. Ni nnkan bii aago meje kọja iṣẹju mẹẹẹdogun alẹ la gbọ pe ina sọ ni ileeṣẹ awọn Ṣaina naa.
Ọkan ninu awọn agba ti wọn fi n sun taya ti wọn n pe ni ‘oven’ lo deede bu gbamu lojiji, ti eeyan mẹẹẹdogun si ku lojiji. Bo tilẹ jẹ pe ọkan ninu awọn ọga ileesẹ naa to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe eeyan mẹta pere lo ku, ti ọpọ si fara pa.
Ọkan ninu awọn ọga to n mojuto awọn oṣiṣẹ naa to pe ara rẹ ni Righteous, ṣalaye pe iṣi meji ni awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ nibẹ. Awọn kan maa bẹrẹ lati aago mẹjọ si mẹfa, awọn mi-in yoo si gba iṣẹ yii ni aago meje alẹ. ALAROYE gbọ pe gẹrẹ ti awọn oṣiṣẹ alẹ gba iṣẹ ni alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii, ko ju iṣẹju mẹẹẹdogun lẹyin ti wọn wọ iṣẹ ti agba naa fi bu gbamu. Mẹfa ni wọn pe agba ti wọn fi n yọ ororo ọhun, ẹyọ kan ninu rẹ lo si bu gbamu, ti ina fi ṣẹ yọ.
Ninu alaye ti Ọgbẹni Righteous ṣe, o ni nnkan kan lo di ọpa to maa n gbe ororo jade ninu agba naa. O ni didi ti nnkan di i lo jẹ ki ohun to yẹ ko raaye jade ko ṣe jade, eyi to fa a ti o fi bu gbamu, ti ina nla si sọ.
Nigba to n ṣalaye bi ileeṣẹ naa ṣe ri, o ni gbogbo awọn nnkan idaabobo to yẹ ki awọn to ba wa nibi iru iṣẹ bẹẹ lo ni ko si. Ko si akoto, ko si bata buutu to yẹ ki awọn maa wọ atawọn nnkan mi-in to le ko awọn yọ ninu iru ewu bayii.
Lasiko to n dahun ibeere akọroyin wa pe boya iru nnkan bẹẹ ti ṣẹlẹ ri nileeṣẹ naa, Supafaisọ yii sọ pe bo tilẹ jẹ pe ko ti i si eyi to tobi to eyi ti awọn ti padanu ẹmi awọn eeyan to to bayii, o ni awọn oṣiṣẹ kan ti padanu awọn ẹya ara wọn lasiko ti wọn n ṣiṣẹ. O ni apa oṣiṣẹ kan ti ge ri, bẹẹ ni awọn kan ti padanu ọwọ wọn.
Siwaju si, ọmọkunrin to ba akọroyin wa sọrọ lede oyinbo naa ṣalaye pe awọn alakooso ileeṣẹ naa ko bikita fun ẹmi ati aabo awọn to n ṣiṣẹ nibẹ rara. O ni bi iṣẹlẹ yii ṣe ṣẹlẹ ni awọn ọga ọhun to jẹ ara Ṣaina ti ba ẹsẹ wọn sọrọ, ti wọn ko si bikita lori awọn oṣiṣẹ wọn. O fi kun un pe bi ijamba kan ba ti ṣẹlẹ, lẹyin akoko diẹ, niṣe lawọn maa tun pada sẹnu iṣẹ bii pe ohunkohun ko ṣẹlẹ, wọn ko si ni i gbe igbesẹ kan pato lati dena iru ajalu yii lọjọ iwaju.
A gbọ pe awọn eeyan to n ṣiṣẹ nileeṣẹ naa to ọgọrun-un meji. Gbogbo awọn nnkan to lewu, to le fa ijamba gidi fun awọn to n ṣiṣẹ nibẹ bii taya la gbọ pe wọn ko si gbogbo agbegbe naa.
Ẹgbẹrun kan aabọ Naira lo ni wọn n san fun awọn oṣiṣẹ lojumọ. Ọpọ igba ni wọn kan maa deede da awọn oṣiṣẹ silẹ lai sọ fun wọn tẹlẹ. Wọn kan le de ibi iṣẹ laaarọ ki wọn sọ pe ki wọn maa lọ sile, iṣẹ wọn ti tan.
Inu igbo ni wọn kọ ileeṣẹ naa si, ti ko si sẹni to le ro pe iru ileeṣẹ bẹẹ wa nibẹ.
A gbọ pe alaga ijọba Ibilẹ Ewekoro, Adeṣina Sikiru Adisa, ti ṣabẹwo si ibi iṣẹlẹ yii. Bakan naa ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ran awọn agbofinro lọ sibẹ.
ALAROYE gbọ pe ileeṣẹ to n mojuto ọrọ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun ti de sibi iṣẹlẹ naa, wọn si n gbiyanju lati ti ileeṣẹ taya ọhun pa lasiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ.
Ọsibitu to wa ni Papalanto ati Sagamu la gbọ pe wọn ko awọn to fara pa nibi iṣẹlẹ naa lọ.