Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
O kere tan, eeyan mẹfa lo ku, ti ọpọ si fara pa yanna-yanna nibi ijamba ọkọ to waye lopopona Ganmọ, nipinlẹ Kwara, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji yii.
ALAROYE gbọ pe ijamba ọkọ naa lo ṣẹlẹ nibi ti ọkọ akero bọọsi Suzuki kan to ni nọmba BDJ-134XB ati ọkọ DAF alawọ buluu ti nọmba rẹ jẹ (ABC435XN) to ko timọọti to n bọ lati ipinlẹ Sokoto fori sọra wọn lojiji. Awọn ti iṣẹlẹ naa soju sọ wọn sọ pe ere asapajude lo sokunfa ijamba ọhun.
Adari ajọ ẹṣọ alaabo oju popo ni Kwara (FRSC), Frederick Ade Ogidan, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni eeyan mẹẹẹdogun lo fara kaasa iṣẹlẹ ọhun, nigba tawọn mẹfa ku. Awọn mẹsan-an fara pa yanna-yanna, ọkunrin si ni gbogbo wọn.
Wọn ti ko awọn to fara pa lọ sileewosan olukọni Fasiti ilu Ilọrin, (UITH), to wa ni Oke-Oyi, fun itọju to peye, ti wọn si ko oku lọ si yara igbokuu-si nileewosan yii kan naa.
aworan jamba ọkọ ni Kwara ree.