Eeyan meji ku nibi ija Hausa atawọn oyinbo China n’Ibokun

Florence Babasola

Eeyan meji; Hausa kan ati oyinbo ara ilẹ China kan ni wọn ti ku bayii nibi wahala kan to bẹ silẹ niluu Obokun l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

ALAROYE gbọ pe awọn oyinbo orileede China ni wọn ko awọn ọlọpaa atawọn sifu difẹnsi lọ sibudo iwakusa kan to wa nibẹ, nibi ti awọn Hausa ti n wa kusa lọna aitọ.

 

 

Awọn ọlọpaa ṣalaye fun awọn Hausa yii pe awọn oyinbo ilẹ China nikan ni ijọba apapọ ati tipinlẹ Ọṣun fun laṣẹ lati wa kusa nibẹ, wọn si ni ki awọn Hausa yii kuro nibẹ.

Ṣugbọn ọrọ naa di wahala, eleyii to yọri si iku Hausa kan, Abdulhadi Musa, ati oyinbo kan, Kuang Zhang.

A gbọ pe wọn tun lu oyinbo kan bii kiku bii yiye, nigba ti ọta ibọn tun ba Hausa kan.

DPO agbegbe naa la gbọ pe o pada lọọ gbe oku awọn mejeeji lọ sileegbokuu-pamọ si ti ileewosan Wesley Guild, Ileṣa, bẹẹ ni Hausa tibọn ba naa n gbatọju lọwọ nileewosan naa.

Leave a Reply