Eeyan meji ku ninu ija aala ilẹ laarin ilu Igboho ati Igbopẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

O kere tan, eeyan meji lo j’Ọlọrun nipe, ti ọpọ eeyan si fara pa, nigba ti awọn araalu Igboho Igbopẹ, nijọba ibilẹ Oorelope, nipinlẹ Ọyọ, gbena woju ara wọn lopin ọsẹ to kọja.

Ilẹ kan to wa lọna ilu Kiṣi, ni ipinlẹ Ọyọ, kan naa, lawọn ilu mejeeji yii n ja si.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ọ pẹ ti awọn ara Igbopẹ ti n fapa janu lori ọrọ ilẹ naa, wọn ni awọn lawọn ni in, ti awọn ara Igboho si n fun wọn lesi pe wọn ko mọ ohun ti wọn n sọ.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, lọrọ doju ẹ nigba ti awọn ọkunrin ilu mejeeji pinnu lati fi eegun ọkunrin yanju ọrọ naa. Lọgan, wọn ti kọ lu ara wọn. Nigba ti yoo si fi to bii iṣẹju mẹwaa pere, ọpọ eeyan ti ṣubu lulẹ nibudo ija, gende meji ninu wọn si ti ku nifọnna-fọnṣu.

Wọn ni ko si nnkan irinṣẹ to le kọja lasiko ija naa, niṣe ni wọn n lọri pada lati sa asala fẹmi-in ara wọn.
Igbiyanju ALAROYE lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ko seso rere pelu bi akọroyin wa ṣe pe SP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe Alukoro ileeṣẹ naa, ṣugbọn ti ko ti i gbe ipe naa titi ta a fi aparo akojọ iroyin yii .

Leave a Reply