Monisọla Saka
Eeyan meji kan ti padanu ẹmi wọn sinu omi okun Baracuda Beach, to wa lagbegbe Abraham Adesanya, Ajah, nipinlẹ Eko. Lọjọ keji ọjọ ọdun Keresi, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun yii, niṣẹlẹ ibanujẹ naa waye nigba tawọn ọkunrin mejeeji ọhun fẹẹ ran ẹni kan tomi naa ti ru bo, to si ti n gbe lọ lọwọ, eyi ni wọn n ṣe lọwọ tomi naa fi ru de, to si wọ awọn naa lọ saarin agbami.
Agbẹnusọ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade to fi lede sọ pe, “Nibi igbafẹ eti okun Baracuda Beach, agbegbe Abraham Adesanya, Ajah, nipinlẹ Eko, ni wọn ti pe wa fun iṣẹlẹ pajawiri kan. Nigba ta a de ibudo iṣẹlẹ naa ni wọn fi ye wa pe awọn eeyan meji kan ti wọn waa gbafẹ leti okun ti ri sinu omi, wọn o si ti i ri wọn gbe jade.
Ninu iwadii ta a ṣe la ti ri i pe awọn gende ọkunrin meji ni wọn padanu ẹmi wọn sinu omi okun yii, lasiko ti wọn fẹẹ doola arakunrin kan tomi okun ru bo, to si ti fẹẹ gbe e lọ. N ni awọn ti omi gbe lọ ba di mẹta.
“Awọn ẹṣọ alaabo ti wọn wa lagbegbe ibi igbafẹ eti okun ọhun ṣalaye pe awọn oloogbe ti tayọ aala, wọn ti rin kọja ibi ti ko yẹ ki wọn de. Bẹẹ lọrọ a n ran ara ẹni lọwọ lai ki i ṣe akọṣẹmọṣẹ lewu lọgangan ibi tomi ti gbe wọn lọ, wọn lawọn o tilẹ faaye gba iru ẹ, nitori idi eyi si ni ẹpa ko ṣe boro mọ, tọrọ fi bọ sori”.
Ọsanyintolu ṣalaye siwaju pe awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti wa nikalẹ gẹgẹ bawọn omuwẹ ṣe n ba iṣẹ lọ lati wa oku awọn eeyan naa gbe jade.