Eeyan mẹrindinlogun ku ninu ijamba mọto lọna Ẹpẹ

Jọkẹ Amọri

L’Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, eeyan mẹrindinlogun lo padanu ẹmi wọn, ti awọn marun-un si tun fara pa ninu ijamba ọkọ kan to ṣẹlẹ niluu Alarọ, loju ọna Ẹpẹ, nipinlẹ Eko.

ALAROYE gbọ pe bi awọn eeyan naa ṣe n wakọ lalẹ ni oju ọna ti wọn n tunṣe lọwọ lo fa wahala ọhun, nitori nnkan bii aago mẹta oru ni ijamba naa ṣẹlẹ gẹgẹ bi ọga to wa ni ẹka ilanilọyẹ nileeṣẹ FRSC, Ọlabisi Sonusi, ṣe fidi rẹ mulẹ.

O ni ọkọ bọọsi funfun kan ti nọmba rẹ jẹ KTN 262YJ ati ọkọ akoyọyọ ni wọn jọ kọ lu ara wọn loru naa, eyi to fa a ti ọkọ mejeeji fi gbina, to si ṣeku pa eeyan mẹrindinlogun, ti awọn marun-un mi-in si fara pa yanna yanna.

Awọn ẹṣọ oju popo yii ni wọn sare gbe awọn to fara pa yii lọ si ọsibitu fun itọju gẹgẹ bi Sonusi ṣe sọ, lẹyin ti wọn yọ oku awọn mẹrindinlogun jade, ti eeyan meji si jade lai fara pa.

Leave a Reply