Florence Babaṣọla, Osogbo
Muslim Saheed, Kazeem Ganiyu ati Ọlalẹyẹ Ọlawale ladajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti sọ pe ki wọn lọọ kẹkọọ diẹ lọgba ẹwọn titi ọjọ tigbẹjọ yoo bẹrẹ lori ọrọ wọn.
Ẹsun ole jija ni wọn fi kan awọn mẹtẹẹta. Gẹgẹ bi Agbefọba, ASP John Idoko, ṣe sọ, aago meje alẹ ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, lawọn olujẹjọ ọhun lọ sile aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Iwọ-Oorun Ọṣun nile igbimọ aṣofin agba, Senetọ Adelere Adeyẹmi Oriolowo.
Nibẹ ni wọn ti ji ọpọlọpọ aṣọ, firiiji, tẹlifiṣan, dikoda, awọn nnkan eelo ile idana atawọn nnkan mi-in. Bi wọn ṣe kuro nibẹ ni wọn tun lọ si oko ọkunrin oloṣelu naa, ti wọn si ji awọn nnkan ti apapọ owo wọn jẹ miliọnu meji naira.
Idoko ṣalaye pe pẹlu ada, apola-igi, irin atawọn nnkan ija oloro mi-in ni wọn lọọ ṣọṣẹ nibẹ lalẹ ọjọ yii, eleyii to lodi si ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.
Agbẹjọro awọn olujẹjọ, I. T. Tẹwọgbade, ta ko gbogbo ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ lẹyin tawọn yẹn sọ pe awọn ko jẹbi, o ni ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ẹsun ole-jija kan wọn niwaju ile-ẹjọ Majisreeti miiran.
Majisreeti Modupẹ Awodele paṣẹ pe ki wọn gbe awọn olujẹjọ mẹtẹẹta lọ sọgba ẹwọn, ki wọn si maa tẹ siwaju ninu igbẹjọ naa nile-ẹjọ Majisreeti ti ilu Iwo ti wọn ti ṣẹ sofin.