Eeyan mẹta ku lasiko ti papa iṣere ti wọn n kọ lọwọ da wo ni Delta

Monisọla Saka

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni apa kan papa iṣere Stephen Keshi International Stadium, ti wọn n kọ lọwọ niluu Asaba, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Delta, wo lulẹ, to si ṣe bẹẹ mu ẹmi eeyan mẹta lọ loju-ẹsẹ.

Apa kan ti wọn n kọ lọwọ ọhun ni wọn n ṣe fun igbaradi ayẹyẹ ọdun ere idaraya lorilẹ-ede yii (National Sports Festival) ti wọn ni yoo waye ni papa iṣere naa lọdun yii. Sunday Dare, ti i ṣe Minisita fọrọ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ ti kọkọ lọọ ṣabẹwo sibi ile tuntun ti wọn n kọ sinu papa iṣere naa fun ilo ajọdun ere idaraya ti wọn fẹẹ ṣe ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ti i le sọ pato ohun to ṣokunfa bi ibi ti wọn n kọ lọwọ ọhun ṣe da wo, sibẹ, wọn ni o le jẹ nitori bi wọn ṣe n sare lati le pari ile naa ko le ba nnkan ti wọn fẹẹ lo o fun laipẹ ọjọ mu.

Leave a Reply