Eeyan mẹta ku ninu ijamba ọkọ l’Ogun

Gbenga Amos, Abẹokuta

Ọsibitu ijọba to wa ni Abẹokuta, ni wọn ko oku awọn eeyan mẹta kan ti wọn padanu emi wọn ninu ijamba ọkọ to waye ni nnkan bii aago meje kọja iṣẹju mẹẹẹdogun aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nitosi agọ ọlọpaa to wa ni Ọbada, loju ọna Marosẹ Eko si Ibadan.

Alukoro ajọ to n mojuto oju popo (FRSC), nipinlẹ Ogun,  Florence Okpe, ṣalaye pe ijamba ọkọ kan lo waye lọjọ naa, nibi ti ọkọ akẹru Volvo kekere kan ti ko ni nọmba ati mọto Nissan kan to ni nọmba AKM489ZY ti kọ lu ara wọn.

Ọkọ akẹru yii la gbọ pe o fi ọna tirẹ silẹ, to lọọ gba ọna ti oni káà yii n gba bọ, ni wọn ba sọ lu ara wọn. Mẹta ninu awọn marun-un ti ijamba naa ba lo ku loju-ẹsẹ, nigba ti awọn meji mi-in fara pa yannayanna.

O fi kun un pe wọn ti ko oku ati awọn to fara pa ninu ijamba naa lọ si ọsibitu ijọba to wa niluu Abẹokuta.

Ọga agba ajọ naa nipinlẹ Ogun, Ahmed Umar, kẹdun pẹlu mọlẹbi awọn ti ijamba naa ba, bẹẹ lo rọ awọn onimọto pe ki wọn maa pa ofin eto irinna mọ.

Leave a Reply