Eeyan mẹta ku, ọpọ fara pa, ninu ijamba ọkọ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn eeyan mẹta ni wọn pade iku ojiji ninu ijamba ọkọ kan to waye lagbegbe ileewe girama ijọba apapọ to jẹ tawọn obinrin, eyi to wa loju ọna marosẹ Akurẹ siluu Ọwọ, niluu Akurẹ, laaarọ kutukutu ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii.

Ijamba yii ni wọn lo waye laarin ọkọ Toyota Sienna kan eyi ti nọmba rẹ jẹ LND 778 YG ati bọọsi Họma ti nọmba tiẹ rẹ jẹ KTN 298 YJ ni nnkan bii aago mẹfa idaji ọjọ naa.

Ni ibamu pẹlu atẹjade ti ajọ ẹsọ ojupopo nipinlẹ Ondo fi sita lori iṣẹlẹ ọhun, eeyan mẹẹẹdogun, ninu eyi ti agbalagba ọkunrin mejila ati obinrin mẹta wa nibẹ ni wọn fara gba ninu ijamba ọhun.

Loju-ẹsẹ ni mẹta ti ku ninu awọn ọkunrin to wa ninu wọn, nigba tawọn mejila yooku fara pa yannayanna.

Ile-iwosan ijọba to wa l’Akurẹ ni wọn sare ko awọn to fara pa lọ fun itọju, ti oku awọn to gbẹmi-in mi sinu iṣẹlẹ ọhun si wa ni mọṣuari ọsibitu yii kan naa.

Awọn ẹsọ ojupopo ni ko sohun meji to ṣokunfa ijamba naa ju iwakuwa ọkọ ati gbigbiyanju lati sare saaju ọkọ mi-in lọna ti ko bofin mu lọ.

Ajọ ọhun waa rọ awọn awakọ lati sọra fun ọkọ wiwa loru ọganjọ latari awọn ewu to rọ mọ ọn. Bẹẹ ni wọn ni ki wọn yago fun ere asapajude, ki wọn si ri i pe wọn n pa ofin to rọ mọ irinna ọkọ mọ. O fi kun un pe awọn ero ọkọ naa lẹtọọ labẹ ofin lati fi ẹjọ awakọ to ba n wa iwakuwa sun awọn ẹṣọ alaabo.

Leave a Reply