Monisọla Saka
Eeyan mẹta lo ti pade iku ojiji nibi iṣẹlẹ ijamba mọto to waye loju titi marosẹ Eko si Ibadan, tawọn mẹta mi-in si fara pa yannayanna. Adari ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC, ẹka ti ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Ahmed Umar, lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kọkanla, ọdun yii, niluu Abẹokuta.
Gẹgẹ bi alaye ti Umar ṣe, laaarọ kutukutu ọjọ Mọnde niṣẹlẹ naa waye lasiko ti ọkọ Toyota Sienna kan to ni nọmba DKP 60 LG, ya bara, to si lari mọ ogiri to da oju ọna marosẹ naa si meji lẹyin ti ijanu ọkọ naa ko ṣiṣẹ mọ.
O ni keeyan too de iyana AP, gẹlẹ ti wọn ba ti kuro ni ileepo Danco, ni ijamba mọto ọhun waye latari ere asapajude to mu ki ijanu ọkọ sọnu, ti awakọ naa ko si ri i du mọ titi to fi lọọ fori sọ ibi kan.
Ọga FRSC ṣalaye siwaju si i pe, “Eeyan mẹfa lo wa ninu ọkọ ọhun, ọkunrin mẹrin atawọn obinrin meji. Mẹta ninu awọn eeyan naa, iyẹn ọkunrin meji ati obinrin kan ni wọn fara ṣeṣe, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe oju-ẹsẹ lawọn mẹta yooku gbẹmii mi”.
Wọn ti gbe awọn mẹta ti wọn fara pa naa lọ si ileewosan Idẹra Hospital, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ, tawọn si ti ko awọn ti wọn padanu ẹmi wọn lọ sile igbokuupamọsi ọsibitu ọhun.
O waa ba awọn ti wọn ni ijamba ọkọ naa atawọn mọlẹbi wọn kẹdun iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun, bẹẹ lo gba awọn awakọ niyanju lati yago fun ere asapajude loju popo, paapaa ju lọ lasiko oṣu baa baa baa to gbẹyin ọdun ta a wa yii.