Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Eeyan bii mẹtalelogun ni wọn ti pade iku ojiji latari ija ilẹ to n waye lọwọ laarin idile meji niluu Igbọkọda ti i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Ilajẹ.
ALAROYE gbọ pe ọdun 2012 lede aiyede lọkan-o-jọkan ti n su yọ laarin Olu ti Igbọkọda, Ọba Afọlabi Odidiọmọ, ati Idile kan ti wọn n pe ni Temetan, lori ọrọ ilẹ, ti wọn ko si ti i ri kinni ọhun yanju titi di ba a ṣe n sọ yii.
Eeyan bii mọkanlelogun ni wọn lo ku ninu rogbodiyan to kọkọ su yọ ninu oṣu karun-un, ọdun ta a wa yii nikan, eyi lo si ṣokunfa bi ijọba atawọn igbimọ ilu ṣe gbimọ pọ lati ṣe agbekalẹ awọn fijilante ti yoo maa pese aabo fawọn eeyan ilu ọhun nigbakuugba ti iru wahala bẹẹ ba tun fẹẹ waye.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, ni wọn ni wahala mi-in tun su yọ lori ọrọ ilẹ naa, tawọn fijilante si mori le ọna ibẹ ki wọn le tete pana rogbodiyan ọhun.
Bi wọn ṣe n debẹ lawọn janduku ọhun sina ibọn bolẹ, ka too wi, ka too fọ, wọn ti pa fijilante kan ti wọn porukọ rẹ ni Aṣọgbọn Ọbayọmi ati oni Maruwa kan to rin sasiko rogbodiyan naa, Idowu Agbude.
Iṣẹlẹ yii lo mu kawọn eeyan ilu Igbọkọda pinnu ati fẹhonu han lọjọ Abamẹta, Satide, ti i ṣe ọjọ ọdun Keresimesi kijọba ipinlẹ Ondo le tete wa nnkan ṣe lori ọrọ ija ilẹ to n fẹmi awọn eeyan ṣofo ọhun.
Awọn to ṣe agbatẹru iwọde ọhun la gbọ pe wọn ti kede, ti wọn si ti kilọ fawọn eeyan pe awọn ko fẹẹ ri ọkọ tabi alupupu loju popo lọjọ ti wọn fi iwọde naa si ki wọn le fi han ijọba bi ọrọ ọhun ṣe ka awọn lara to.
Lẹyin-o-rẹyin ni wọn tun pada kede pe awọn ti fagi le ifẹhonu han ọhun nitori pe awọn ko ni i fẹ kawọn araalu fi inira ṣọdun Keresi.
Alaga ijọba ibilẹ Ilajẹ, Ọnarebu Ọlamigoke Jatuwaṣe gba awọn eeyan Igbọkọda nimọran lati gba alaafia laaye lasiko ọdun yii.
O ni awọn ẹsọ alaabo tijọba ṣeto ti wa nikalẹ lati ri i pe awọn eeyan ko huwa to le da ilu ru.
Jatuwaṣe ni oun nigbagbọ pe ohun gbogbo ko ni i pẹẹ pada sipo niluu Igbọkọda nitori oun ti lọ siluu Akurẹ lati fi iṣẹlẹ ọhun to gomina leti.