Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Eeyan mẹwaa ni wọn ṣe kongẹ ọlọjọ wọn nibi ijamba ọkọ to waye l’ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ti i ṣe ọjọ ayẹyẹ ọdun Ileya, ni nnkan bii aago mẹrin, irọlẹ lagbegbe Iyemọja, Opopona Olooru-Okoolowo, Ilọrin, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.
Mọto elero mejidinlogun kan to ni nọmba LND 742XK, lo takiti latari ere asapajude to n sa lagbegbe Iyemọja, opopona Olooru-Okoolowo si Jẹbba. Eeyan mẹwaa lo ku ninu ijamba naa, ọpọ si fara pa yanna yanna.
Ọga agba ajọ ẹsọ alaabo oju popo (FRSC), ẹka ti ipinlẹ Kwara, Jonathan Owoade, lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni ijamba ọkọ naa waye latari ere buruku ti awakọ naa sa. O tẹsiwaju pe ijamba naa lagbara to bẹẹ to jẹ pe eeyan mẹwaa lo ku loju ẹsẹ, tawọn miiran si fara pa yanna yanna.
Ọwọade ni gbogbo awọn to fara pa ni ikọ awọn ti ko lọ si ileewosan aladaani kan ti orukọ rẹ n jẹ Ayọ, to wa ni lagbegbe Okoolowo, niluu Ilọrin, fun itọju to peye. Bẹẹ ni wọn ti ko awọn oku lọ si yara igbooku-si nileewosan ijọba. Ọwọade ki ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, kuusẹ gẹgẹ bii wọn ṣe ran ajọ naa lọwọ lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye. Bakan naa lo rọ awọn awakọ lati maa bọwọ fun ofin irinna oju popo, ki ijamba le dinku lawọn ọna wa.