Adewale Adeoye
Awọn alaṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku lorileede wa, Economic And Financial Crimes Commission (EFCC), ti ṣekilọ pe awọn yoo maa fọwọ ofin mu ẹnikẹni to ba ṣe fiimu atawọn to n ṣere keekeeke ‘Skit-Makers’ ti wọn n lo aṣọ ajọ naa ati gbogbo ohun idanimọ awọn lai jẹ pe wọn gba iyọnda lọwọ awọn ki wọn too ṣe bẹẹ.
Alukoro ajọ ọhun, Ọgbẹni Wilson Uwajeren, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita lorukọ ajọ yii.
Ẹda atẹjade ọhun to tẹ ALAROYE lọwọ sọ pe ofin to gbe ajọ ọhun kalẹ ko faaye gba pe ki ẹnikẹni maa lo awọn ohun idanimọ wọn bii: aṣọ penpe ti wọn maa n wọ soke ti wọn n pe ni jakẹẹti, kaadi idanimọ ati amin wọn ti wọn n pe ni logo, lati maa fi ṣere ori itage, fiimu agbelewo tabi awọn ere oniṣẹju diẹ ‘Skit’ ti wọn maa n lo o fun tẹlẹ.
O ni ohun ti ẹnikẹni to ba fẹẹ lo awọn ohun idanimọ ajọ naa gbọdọ kọkọ ṣe ni ko yọju sọdọ awọn lati gba iyọnda ko too lo ohun kohun nipa awọn.
Wilson ni, ‘A ko sọ pe ki wọn ma lo awọn ohun idanimọ wa lati fi ṣere ninu fiimu agbelewo gbogbo to n jade lorile-ede Naijiria, ohun ta a n sọ ni pe ki wọn kọkọ waa gba iyọnda lọwọ wa ko too di pe wọn lo awọn nnkan naa. Ofin to gbe ajọ naa kalẹ ko sọ pe ki ẹnikẹni maa lo awọn ohun idanimọ wa lati maa fi ṣere lasan lai gba aṣẹ lọwọ wa. Ẹni ta a ba mu pe o lo awọn ohun naa lai gba iyọnda lọwọ wa yoo fimu kata ofin.