EFCC kilọ fawọn adẹrin-in-poṣonu: Ẹ yee maa lo aṣọ wa lati fi ṣere o

Adewale Adeoye

Oogun awitẹlẹ lawọn agba ni ko gbọdọ pa arọ, iyẹn arọ to ba gbọn ni o. Ni bayii, awọn alaṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku laarin ilu ‘Economic And Financial Crimes Commission’ (EFCC), ti lawọn ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ awọn adẹrin-in-poṣonu gbogbo lorileede yii ti wọn n lo awọn ohun eelo bii aṣọ wọn atawọn nnkan mi-in to jẹ ti ajọ naa lati maa fi ṣere lori ẹrọ ayelujara mọ.

Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti ṣekilọ pe awọn ko ni i fojuure wo awọn adẹrin-in-poṣonu gbogbo lorileede yii ti wọn ba tun lo awọn ohun eelo awọn lati maa fi ṣawada, paapaa ju lọ eyi kan ti wọn ṣe laipẹ yii, nibi ti wọn ti tabuku nla ba ajọ naa lori ayelujara.

Atẹjade ọhun lọ bayii pe, ‘’A ki i ṣe ajọ yẹpẹrẹ rara laarin ilu, ẹni ọwọ, ẹni apọnle la jẹ, fidio oniṣẹẹju diẹ kan ti wọn pe ni ‘EFCC and Army wahala’ la fẹẹ tọka si bayii. Loootọ, fidio naa ti pẹ diẹ, ṣugbọn lara pe a ko fẹ iru rẹ mọ la ṣe n ṣekilọ fawọn adẹrin-in-poṣonu gbogbo lorileede yii pe ki wọn ma ṣe dan iru aṣa bẹẹ wo mọ, a ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ awọn ti wọn maa n lo awọn ohun to jẹ mọ ajọ naa lati maa fi ṣawada laarin ilu mọ, ẹni ba leti ko gbọ, a maa fẹni tọwọ ba tẹ jofin ni’’. Bẹẹ ni EFCC sọ.

 

 

Leave a Reply