EFCC mu oludasilẹ ijọ ati pasitọ to ran pe ko gbe oogun oloro lọ siluu oyinbo

Ọrẹoluwa Adedeji

Ajọ to n gbogun ti tita ati gbigbe oogun oloro nilẹ wa (EFCC), ko fu ọkunrin kan, Olori Alufaa Nnodu Nzuka Kenrick, to pe ara rẹ ni oludasilẹ ṣọọsi kan ti wọn n pe ni Seraphic and Sabbath Assembly, to wa ni No 1, Sabbath Close, Ijẹṣa, nipinlẹ Eko, lara rara ti wọn fi ya bo ile rẹ, ti wọn si gbe e janto lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Keji yii; iyẹn lẹyin ti ọkan ninu awọn ọmọọṣẹ rẹ ti jẹwọ pe oun lo n fi oogun oloro ran awọn lati fi ranṣẹ si Oke-okun.

Ọkunrin yii ni wọn ni oun ati pasitọ mi-in to n kẹkọọ lọwọ ni ileewe awọn oniwaasu kan ti wọn pe ni Emmanuel College of Technology, Samanda, Ibadan, Udezuka Udoka, ati obinrin to maa n ṣe agbodegba fun wọn, Oyoyo Mary Obasi, ni wọn jọ n lọwọ ninu gbigbe ati tita oogun oloro ọhun.

Gẹgẹ bi Alukoro ajọ EFCC, Fẹmi Babafẹmi, ṣe ṣalaye ninu atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ, o ni ọwọ tẹ awọn eeyan naa lasiko ti wọn n gbiyanju lati gbe oogun oloro ti wọn n pe ni methampethamine ati skunk, ti wọn ko pamọ sinu kẹẹgi epo pupa, lọ si Dubai, lorileede United Arab Emirate. Ileeṣẹ kan to maa n ba wọn fi ẹru ranṣẹ, to si tun maa n ba wọn gba ẹru lati Oke-okun ti wọn n pe ni NAHCO, to wa ni papakọ ofurufu Murtala Mohammed, niluu Ikẹja, ni wọn fẹẹ gbe ẹru naa ran ti ọwo fi tẹ Mary to jẹ agbodegba wọn to fẹẹ lọọ fi ẹrun ti ko bofin mu ọhun ranṣẹ.

Oyoyo ati Udoka ni wọn kọkọ ri mu lọjọ kẹsan-an, oṣu Keji yii, pẹlu idi oogun oloro skunk to din diẹ ni ọọdunrun (283), ti giraamu rẹ si fẹrẹ to mẹẹẹdogun (14.90) ati giraamu methamephine to le mẹrin ni igba (204), eyi ti wọn ko pamọ sinu kẹẹgi epo pupa, ti wọn fẹẹ fi ranṣẹ si Dubai.

Nigba ti wọn fọrọ po wọn nifun pọ, Mary jẹwọ pe oludasilẹ ṣọọṣi ti oun ṣẹṣẹ bẹrẹ si i lọ laipẹ yii lo ran oun ni iṣẹ buruku naa.

O ni oun ati ọmọ rẹ ti wọn n pe ni Chisom Obi, ẹni to ti na papa bora bayii ni wọn maa n gbe oogun naa fun oun pe ki oun lọọ gbe e ranṣẹ si Dubai, lẹyin ti wọn ti ni ki oun mulẹ pe ẹnikẹni ko ni i gbọ nipa ohun ti awọn n ṣe yii. O fi kun un pe odidi adiẹ kan ni pasitọ yii pa sinu ṣoọṣi lati fi ṣe irubọ, lẹyin eyi ni yoo si tun gbadura foun pe alọbọ ti ọwọ n lọ sẹnu loun maa lọ, ti oun si maa pada de.

Mary ni nigba ti oludasilẹ ijọ yii ati ọmọ rẹ mọ pe oun ti mọ aṣiri awọn ni wọn maa n halẹ mọ oun, ti wọn si fi tipa mu oun pe ki oun maa ṣiṣẹ ti ko bofin mu naa, eyi ti wọn n pe ni

Ice ati Bibeli iyẹn orukọ adape ti wọn fun (methamephine ati igbo).

Udezuk ni wọn fa Mary ti oun ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣe egboogi oloro yii le lọwọ pe ko maa tọ ọ sọna. Ọmọkunrin to wa nileewe ẹkọ awọn oniwaasu naa ni miliọnu meji Naira ni wọn fun oun fun iṣẹ ti wọn gbe le oun lọwọ yii, oun ko si le kọ ọ nitori oun nilo owo fun ileewe ti oun n lọ.

 

Leave a Reply