EFCC mu ọmọleegbimọ aṣofin fẹsun jibiti, owo rẹpetẹ ni wọn ba lọwọ ẹ

Jọkẹ Amọri

Miliọnu lọnaa ọọdunrun o le mẹrindinlogbọn Naira, (326m) ati ẹgbẹrun lọna ogoje owo dọla le ẹẹdẹgbẹta($140,500)ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ wa, ka mọ ọkan ninu awọn ọmọleegbimọ aṣofin ipinlẹ Kogi,  to tun jẹ oludije sipo ileegbimọ aṣofin ninu eto idibo ọdun to n bọ labẹ ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples party, Ismaila Atumeyi lowo. Ni wọn ba gbe e janto, wọn ni ko waa ṣalaye ibi to ti ri awọn owo naa.

Opopona kan ti wọn n pe ni Mercedonia, ni adugbo Queen Estate, to wa ni Karsana, Gwarinpa, l’Abuja, ni wọn ti mu un lojọ Aiku, Sannde, ọgbọnjọ, oṣu Kẹwaa, to ṣẹṣẹ pari yii, fẹsun iwa ọdaran. Oun nikan kọ ni wọn mu, ọwọ tun ba ọmokunrin kan toun jẹ ogbologboo ninu jibiti lilu, Joshua Dominic. Bakan na ni wọn mu AbdulMalik Fẹmi toun ti figba kan jẹ oṣiṣẹ ọkan ninu awọn banki ilẹ wa.

Fẹmi yii ni wọn lo maa n tu aṣiri awọn banki yii, to si maa n fọna ti wọn le gba lu wọn ni jibiti han awọn ẹlẹgbẹ rẹ. Ṣugbọn ilu Eko ni wọn ti mu oun ni otẹẹli Radisson Blu, to wa ni Ikẹja. Awọn EFCC ko si fakoko ṣofo ti wọn fi ni ko maa niṣo ni ile rẹ to wa ni Morgan Estate, Ojodu, niluu Eko kan naa.

Nigba ti wọn de ile atilaawi, ẹgbẹrun lọna ọtalenirinwo owo dọla ($460,000) ni wọn ba ninu ile rẹ.

O pẹ diẹ tawọn ọlọpa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni ọkan ninu awọn banki ilẹ wa, nibi ti awọn eeyan naa ti lu banki ọhun ni jibiti owo to le ni biliọnu kan Naira(1.4b). Fẹmi yii wa lara awọn ti wọn lu jibiti yii gẹge ba a ṣe gbọ.

Dominic yii ni wọn ni aṣofin Kogi yii mọ, to si tun mu un mọ Fẹmi to jẹ ki wọn ri iṣẹ naa ṣe. Joshua yii ni wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii onijibiti pọnble, ọpọ igba lawọn olọpaa ti mu un fẹsun jibiti.

Leave a Reply