EFCC ti mu awọn eleyii, kusa ni wọn wa lọna aitọ n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Akolo ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka tilu Ilọrin, ni awọn afurasi mẹsan-an kan, Waliu Abidoye, Abubakar Auwal AbdulRauf Hakim, Sabiu Usman, Salihu Godwin, Dauda Mohammed ati Ọlamilekan Arẹmu wa bayii. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn wa kusa lọna aitọ niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan Faleti Waheed ati Noah Ọlamilekan pe wọn fẹẹ fun awọn oṣiṣẹ ajọ naa kan ni riba, ki wọn le tu wọn silẹ lẹyin tọwọ tẹ wọn tan.

ALAROYE gbọ pe awọn afurasi mejeeji yii ni wọn ko miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba Naira (1.2m) fun awọn oṣiṣẹ ajọ naa gẹgẹ bii owo kọbẹ, ki wọn le tu ọkọ tirela ti wọn fi n ko awọn ẹru ofin ọhun silẹ layọ ati alaafia, ṣugbọn ti ẹkọ ko pada soju mimu fun wọn, nitori awọn yẹn ko gba owo ọhun lọwọ wọn, ni EFCC ba ti wọn mọlẹ.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ ajọ naa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Dele Oyewale, ṣe wi, o ni lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, lọwọ tẹ awọn afurasi naa niluu Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, tawọn si ri awọn ọkọ tirela ti wọn fi n ko ẹru ofin ọhun to n lọ bii marun-un gba lọwọ wọn.

O tẹsiwaju pe iwadii fidi ẹ mulẹ pe awọn afurasi naa ko gba iwe aṣẹ lọdọ awọn alaṣẹ, bakan naa ni wọn ko san owo to yẹ fun ijọba apapọ gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ.

Ajọ naa ni awọn yoo foju awọn afurasi yii bale-ẹjọ lẹyin ti gbogbo iwadii ba pari lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Leave a Reply