EFCC ti mu ọkan lara awọn minisita Buhari o

Adewale Adeoye

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku nilẹ wa ‘Econmic And Financial Crimes Commission’ (EFCC), ti fọwọ ofin mu minisita to n ri sọrọ obinrin lorileede yii nigba iṣakoso ijọba  Buhari, Abilekọ Pauline Tallen. Ẹsun pe o ko bilionu meji Naira jẹ ni wọn fi kan an.

ALAROYE gbọ pe funra Pauline lo fẹsẹ ara rẹ rin lọọ ba ajọ EFCC ọhun ni ọfiisi wọn kan to wa niluu Abuja, lẹyin tawọn yẹn ti kọkọ fiwe pe e tẹlẹ pe ko waa sọ tẹnu rẹ nipa owo biliọnu meji Naira kan ti wọn lo ko sapo ara rẹ. Nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjo keji, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni Pauline de sinu ọgba ajọ EFCC naa, ti wọn si n bi i leere awọn ibeere kọọkan, eyi tawọn kan ti wọn ri Pauline lakooko naa sọ pe ṣe ni minisita ọhun n laagun gidi ninu ọyẹ nitori pe ko mọ rara pe wọn le tuṣu ọrọ owo naa de isalẹ ikoko rara.

Titi di nnkan bii ago mẹjọ kọja iṣẹju diẹ ni aṣaalẹ ọjọ Furaidee, ni Pauline ṣi fi wa lọdọ ajọ EFCC yii, ti wọn ko ti i gba ko maa lọ sile rẹ nitori wọn sọ pe ko ti i sọ awọn ohun kọọkan tawọn fẹẹ gbọ lati ẹnu rẹ sita.

Eyi to ja si pe, o ṣee ṣe ko jẹ pe ọdọ awọn FFCC ni Pauline ṣi wa lasiko ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Bẹ o ba gbagbe, ọsẹ yii kan naa ni wọn bẹrẹ iwadii owo kan bayii ti wọn ni gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ọgbẹni Fayemi, ko jẹ. Wọn ni ko waa sọ bo ti ṣe ṣowo ipinlẹ naa lakooko to fi wa nipo gomina.

Leave a Reply