EFCC ti mu Shuaib, ọpọlọpọ igbo ni wọn ba lọwọ ẹ n’Ilọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ nilẹ yii, EFCC ti mu arakunrin ẹni ọdun marunlelọgọta kan, Musa Shuaib, fẹsun pe o n gbe ọpọlọpọ pasu igbo kiri lagbegbe Adewọle, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, ọṣẹ to kọja yii, ni ọwọ tẹ ọkunrin naa pẹlu ọpọlọpọ igbo lagbegbe Adewọle, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin (West) Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti ko si ri alaye kankan ṣe fun ajọ naa nipa bi igbo naa ṣe jẹ, to si ti n ṣẹju pẹu ni galagala EFCC bayii.

Bakan naa ni wọn tun mu arakunrin kan Butven Siman, ẹni ọdun mejilelọgọta, labule Timbol, ni Guusu Lang village tang, nipinlẹ Plateau, fẹsun gbigbe egboogi oloro.

 

Leave a Reply