Ọrẹoluwa Adedeji
Ni bayii, ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkunmọkun nilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ti ju ọmọkunrin to maa n mura bii obinrin nni, Idris Okunnẹyẹ, ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky silẹ lahaamọ wọn, lẹyin ọpọ wakati ti wọn ti fọrọ po o nifun pọ.
Nigba ti wọn beere bi ọrọ ṣe jẹ lori fọnran kan to gba ori ayelujara, nibi ti Mummy of Lagos ti n ba ẹnikan sọrọ, to si sọ pe miliọnu mẹẹẹdogun Naira loun fun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ki wọn le fi yọ ẹsun pe oun n ba awọn eeyan ṣe agbodegba owo, eyi ti wọn n pe ni money lundering lọrun oun.
Bobrisky ni ohun ko mọ ohunkohun nipa fọnran naa, nitori oun ko ba ẹnikẹni sọrọ. O fi kun un pe oun ko fun ẹnikẹni lowo, bẹẹ ni ko si oṣiṣẹ ijọba kankan to beere owo lọwọ oun, bi ẹni to si gbe fọnran naa jade ba ni ẹri kan to fi le gbe e lẹsẹ pe oun loun n sọrọ ninu fọran naa, ko mu un sita.
Eyi lo mu ki ileeṣẹ amunifọba naa gba beeli Bobrisky, ti wọn si tu u silẹ pe ko maa lọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ Keji, oṣu yii.
Lọsẹ to kọja yii ni wọn ṣu Mummy of Lagos rugudu kuro ninu baaluu KLM, to n lọ si Amsterdam, nibi ti ọmọkunrin yii iba ti wọn baaluu mi-in ti yoo gbe de London to n lọ.
O ti wa ninu ẹronpileeni, o ti kẹru sọkọ, ki baaluu gbera lo ku ti gbogbo rẹ fi di gidigidi ninu ọkọ, naa, ti awọn ẹṣọ to n mojuto iwọle ati ijade ero nilẹ wa ati ajọ EFCC fi nawọ gan an. Bo tilẹ jẹ pe oun naa ja fitafita, to si n pariwo pe ki ọmọ Naijiria gba oun, gbogbo eyi ko turun kan lara awọn amunifọba naa, niṣe ni wọn wọ ọ jade, to si pada fi ẹsẹ ṣeṣe nibi ti wọn ti jọ n fa a.
Lẹyin ti wọn gbe e kuro ni papakọ ofurufu ọhun, ilu Abuja ni wọn gbe e lọ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn aṣofin gbe igbimọ dide nipa iṣẹlẹ to tun kan ileeṣẹ ọgba ẹwọn ilẹ wa yii, wọn da Bobrisky lare pe irọ ni gbogbo ohun to wa ninu fọnran naa. EFCC ni awọn ti ranṣẹ pe e laimọye igba pe ko waa ṣalaye awọn oṣiṣẹ wọn to ni wọn fun oun lowo, ibi ti wọn ti gba a ati awọn to gba owo naa lọwọ rẹ, ṣugbọn ṣe ni ọmọkunrin naa kọ eti ọgbọnin si ipe awọn, o kọ ko waa jẹ awọn. Eyi ni wọn lawọn tori ẹ gbe Bobrisky lọ si Abujako too di pe wọn da a silẹ.
Ṣugbọn awọn kan ti n bu ẹnu atẹ lu ajọ amunifọba naa, wọn ni kin ni awọn eeyan naa n wo latigba ti iṣẹlẹ naa ti waye ti wọn ko lọọ mu Mummy of Lagos. Wọn ni ki i ṣe pe wọn ko mọ ibi ti ọmọkunrin naa wa tabi ibi to n gbe, ki lo waa de to jẹ asiko to n rinririn-ajo kuro ni Naijiria ni wọn lọọ mu un, ti wọn si tun ṣe e leṣe.
Ju gbogbo rẹ lọ, Mummy of Lagos ti kuro lakata EFCC niluu Abuja, ginni ti adiẹ ẹ toko eemọ bọ ni ki ọmọkunrin naa pada sile rẹ.