Adewale Adeoye
Ajọ kan to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu ni mọku-mọku lorileede yii, ‘Economic And Financial Crimes Commission’ (EFCC) ti sọ pe awọn ọmọ Yahoo tiye wọn jẹ mẹrindinlọgbọn lọwọ awọn ti tẹ bayii, tawọn yoo si foju gbogbo wọn pata bale-ẹjọ ni gbara tawọn ba ti pari iwadii tawọn n ṣe nipa wọn.
ALAROYE gbọ pe awọn agbegbe bii: Kubwa, niluu Abuja, ni ajọ naa ti lọọ fọwọ ofin mu gbogbo awọn oniṣẹ ibi yii l’Ọjọbọ, Toside, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.
Awọn ọmọ Yahoo tọwọ ajọ naa tẹ ni: Favour Obinna, Chinaza Onuigbo, Abdulrahman Ibrahim, Suleiman Daude, Ali Daude, Godwin Ifeanyi, Victor Ageme, Enoch Alfa, Wildom Ndubuisi, Mathew Gideon, Stanly Kosi, Japhet Akogun, James Efegba ati Christopher Enaho.
Lara awọn ẹru ofin ti wọn ri gba lọwọ wọn ni mọto Toyota Camry S.E kan, mọto Mercedes Benz GLK 350 kan ati Lexus I.S 259 meji ati ọpọlọpọ foonu igbalode.
Wọn ni gbara tawọn ba ti pari gbogbo iwadii awọn tan lori awọn ọmọ Yahoo naa lawọn maa foju gbogbo wọn bale-ẹjọ lati le jiya ẹṣẹ ti wọn ṣẹ.
Nítorí ẹbọ ti wọn ba lorita ilu wọn, idaamu nla ba awọn eeyan ilu Ọwẹna, wọn ni ami buruku ni