Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Oru ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, ki i ṣe eyi ti yoo ṣee gbagbe bọrọ fawọn ọmọ jayejaye kan pẹlu bi ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ajẹbanu lorilẹ-ede Naijiria, (EFCC) ṣe ya bo wọn lojiji nibi ti wọn ti n ṣe faaji ninu ile-ijo kan to wa lagbegbe Alagbakam niluu Akurẹ, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe pupọ ninu wọn lọ.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago kan oru ni wọn lawọn ẹṣọ alaabo ọhun de si gbaju gbaja ile-ijo ta a n sọrọ rẹ yii, ti wọn si n yinbọn soke kíkankíkan lati fi dẹru ba awọn eeyan, bẹẹ ni wọn tun n yin tajutaju lati fi ṣọkọ fawọn to ba fẹẹ gbiyanju lati ba wọn figa gbaga lasiko naa.
Awọn eeyan to le laaadọta, ninu eyi ta a ti ri ọkọ iyawo kan toun atawọn ọrẹ rẹ jọ waa ṣe ajọyọ aisun alẹ igbeyawo (Bachelor’s eve) ni wọn ni EFCC fipa ko lọ lori ẹsun pe afurasi ogbontarigi ọmọ Yahoo ni wọn.
Koda, a gbọ pe awọn ṣọja meji ni wọn fara pa lasiko tawọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ọhun fi pa itu ọwọ wọn ninu ile-ijo ta a n sọrọ rẹ yii.
Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ awọn ti wọn fi pampẹ ofin gbe ni awọn ọkọ ayọkẹlẹ olowo nla, ọpọlọpọ kọnputa agbeletan, awọn foonu olowo nla atawọn ẹru mi-in.
Ohun ta a gbọ lasiko ta a n ko iroyin yii jọ lọwọ ni pe awọn ọdọ kan ti n ko ara wọn jọ niluu Akurẹ lati fẹhonu han ta ko igbesẹ naa, wọn ni awọn eeyan ti wọn ko yii ko ti i ṣẹ sofin rara lori pe wọn ko ara wọn jọ sibi kan lati jaye ori wọn.