EFCC ya bo ilu  Ẹdẹ, ọmọ Yahoo mẹrinlelọgọta ni wọn ko

Faith Adebọla

 Niṣe lọrọ di ẹni ori yọ o dile laarin awọn afurasi ọdaran ti wọn n lu jibiti ori ẹrọ ayelujara, eyi ti wọn n pe ni Yahoo-Yahoo l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un yii, niluu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun. Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti, ajẹbanu ati pipa owo ilu ni pompo nilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), lo ya bo awọn gende-kunrin rẹpẹtẹ kan lawọn ibuba wọn ti wọn ti n ṣe okoowo gbaju-ẹ wọn niluu iṣẹmbaye ọhun, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe mẹrinlelọgọta (64) lara wọn. Wọn tun ko gbogbo ọkọ ayọkẹlẹ bọginni, ẹrọ kọmputa ati foonu alagbeeka ti wọn ka mọ wọn lọwọ lọ.

Ninu atẹjade kan ti EFCC fi lede lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un ta a wa yii, wọn lo ti pẹ ti olobo ti n ta wọn nipa iwa arufin tawọn afurasi naa n hu, bi wọn ṣe fẹẹ sọ ilu Ẹdẹ di ikorita ẹkọṣẹ Yahoo-Yahoo, ati iwa ọmọ jayejaye ti wọn hu kiri igboro. Eyi lo mu kawọn tubọ fimu finlẹ daadaa, wọn wa gbogbo ibuba, otẹẹli, ati kọlọfin ti wọn sa pamọ si, ki wọn too ya bo wọn lojiji lọjọ Wẹsidee ọhun.

Nigba ti wọn ko wọn, lara dukia ati irinṣẹ ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni ọkọ ayọkẹlẹ bọginni bọginni mejidinlogun, foonu olowo nla oriṣiiriṣii mejilelaaadọfa (112) ẹrọ kọmputa agbeletan mejidinlogun (18), ẹrọ iṣere kọmputa, iyẹn Play Station games mẹta, ọkada marun-un, ati ọpọlọpọ awọn iwe-aṣẹ, iwe-ẹri to jẹ ayederu ni gbogbo wọn, bẹẹ ni wọn tun ba oogun abẹnugọngọ.

EFCC ti ni gbogbo awọn ti wọn ko yii ni yoo foju bale-ẹjọ lẹyin ti iwadii to lọọrin nipa ẹsun ti wọn fi kan wọn ba ti pari.

Leave a Reply