EFFC gbe Okorocha lọ si kootu, gomina tẹlẹ naa loun ko jẹbi

Monisọla Saka

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Imo, Rochas Okorocha, ti rawọ ẹbẹ si ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan an pe oun ko jẹbi ẹsun mẹtadinlogun ọrọ arọndarọnda owo ti ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC, fi kan oun atawọn mẹfa kan.
Okorocha to wọnu igi igbẹjọ ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ku iṣẹju marundinlọgbọn, loun ati oloye kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Anyim Nyerere Chinenye, atawọn ileeṣẹ marun-un kan, iyẹn – Naphtali International Limited, Perfect Finish Multi Projects Limited, Consolid Projects Consulting Limited, Pramif International Limited, ati Legend World Concepts Limited bẹrẹ si i bẹbẹ.
Nigba ti wọn ka igbẹjọ ọhun setiigbọ wọn niwaju Onidaajọ Inyang Ekwo, gomina ana nipinlẹ Imo naa sọ pe, “Ọrọ ẹsun ti wọn fi kan mi ye mi, amọ, Oluwa mi, mi o jẹbi”.
Awọn olujẹjọ yooku naa bẹbẹ pe awọn o jẹbi nibi ijẹjọ to waye lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.

Okorocha to jẹ oun lo tukọ ijọba ipinlẹ Imo lati ọdun 2011 titi di ọdun 2019 ni wọn fẹsun kan pe o ṣe afọwọra owo to jẹ ti ipinlẹ Imo to fẹrẹ to biliọnu mẹta Naira (2.9 billion) bẹẹ ni wọn tun fẹsun ilẹdi apo pọ ati ole jija kan an.

EFCC tun fẹsun kan awọn olujẹjọ pe wọn ko owo ninu apo ijọba ipinlẹ Imo ati ti agbarijọpọ awọn ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Imo, wọn si wọ owo ọhun sinu apo awọn ileeṣẹ aladaani kan.
Gẹgẹ bi awọn ti wọn n gbogun ti iṣowo ilu mọkumọku ati iwa ibajẹ ṣe sọ, wọn lawọn olujẹjọ yii ṣe awọn ohun ti wọn fẹsun rẹ kan wọn yii laarin oṣu Kẹwaa, ọdun 2014, si oṣu Keji, ọdun 2016.
Okorocha to tun jẹ Sẹnetọ to n ṣoju ipinlẹ Imo nileegbimọ aṣofin agba bayii naa wa ninu awọn to gba fọọmu lati dupo aarẹ Naijiria. Ṣugbọn ko jọ pe erongba rẹ yii yoo wa si imuṣẹ pẹlu bo ṣe jẹ pe wọn ti bẹrẹ si i ṣe ayẹwo fun awọn oludije, ti ile-ẹjọ si ni ki wọn maa mu oun lọ si akata awọn EFCC.
Kikọ ti wọn lo kọ lati yọju sibi igbẹjọ lo mu ki EFCC wa fi panpẹ ofin gbe e lọsẹ to kọja yii.

Leave a Reply