Adewale Adeoye
Awọn alaṣe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti sọ pe awọn ti gbọ si iṣẹlẹ bi ọkunrin kan, Sanusi Abdulwahab, ṣe fibinu lu ọkan lara awọn ọmọ rẹ, Oloogbe Mustapha Sanusi, ẹni ọdun mẹrindinlogun, pa nitori ọka-baba lasan.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, S.P. Abdullahi Haruna Kiyawa, to sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keje, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, fidi rẹ mulẹ pe ẹnikan kan to n gbe lagduugbo ibi ti baba ọmọ ọhun n gbe toju rẹ ko gba iwa ọdaju to hu naa lo waa fọrọ Ọgbẹni Sanusi to awọn ọlọpaa.
O ni loju-ẹsẹ tawọn ọlọpaa agbegbe Tanagar, nijọba ibilẹ Warawa, ti gbọ sọrọ naa ni won ti lọọ fọwọ ofin mu un, ko le waa sọ tẹnu rẹ lori ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ lori iku ọmọ naa.
Haruna ni, ‘‘Awọn to wa nitosi nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni wọn sare waa fọrọ ọhun to wa leti, ta a si ti lọọ fọwọ ofin mu un lori ohun to ṣe yii.
‘‘Sanusi ti i ṣẹ baba oloogbe naa bẹrẹ si i lu ọmọ rẹ nilukulu lọjọ naa ni, ẹsun pe ọmọ ọhun lọọ ji ọkababa rẹ bu nibi to gbe si i lo fi kan an. Gbogbo bawọn eeyan, paapaa ju lọ awọn tọrọ naa ṣoju wọn ṣe n bẹ ẹ pe ko dariji ọmọ naa, ẹyin eti rẹ lo n bọ si.
‘‘O loun yoo lu u daadaa lati le jẹ ẹkọ nla fun un pe ole jija ki i ṣohun to daa rara. Nibi to ti n lu ọmọ ọhun ni ibawi ọhun ti gbodi lara rẹ, to si gbabẹ ku, loju rẹ ba walẹ pẹsẹ.
‘‘A maa bẹrẹ iwadi wa lọsẹ yii, ta a si maa foju rẹ bale-ẹjọ lẹyin ta a ba pari gbogbo iwadii wa tan, ko le lọọ fimu kata ofin lori ohun to ṣe yii, nitori ofin ipinlẹ yii ko faaye gba a rara pe keeyan lu ọmọ to bi ninu ara rẹ pa.’’