Ismail Adeẹyọ
Yoruba bọ, wọn ni ‘ọmọ iya ki i ya, ọmọ baba ni i ba’, ṣugbọn ọrọ yii ko ri bẹẹ rara lọdọ ọkunrin kan ti wọn n pe ni Ekpong, latari bo ṣe yinbọn pa ẹgbọn ẹ nitori oko ọpẹ ti wọn jogun lọdọ baba wọn.
Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Cross Rivers, ti mu afurasi ọdaran yii, ẹsun ti wọn tori ẹ mu un ni pe lẹyin to yinbọn pa ẹgbọn ẹ, o tun kun un wẹlẹwẹlẹ bii ẹran Ileya.
Iṣẹlẹ abami ọhun ni wọn lo ṣẹ nigba ti ọmọkunrin yii ba ẹgbọn rẹ, Ofrekpe, ninu oko baba wọn to n kọ ọpẹ lọwọ. Ekapong ko ro o lẹẹmeji to fi yinbọn lu ẹgbọn rẹ, nigba to ri i pe ẹlẹkọ ọrun ti polowo fun un lo yọ ọbẹ ti i, to si bẹrẹ si i kun un bii ẹran.
Obinrin kan torukọ rẹ n jẹ Alice, to jẹ ọmọ oloogbe ọhun, ṣalaye fawọn oniroyin pe, ‘‘Lọjọ tiṣẹlẹ buruku yii waye, aburo baba mi torukọ rẹ n jẹ Ekapong lọ sinu oko to jẹ ti baba awọn mejeeji, o si ri baba mi nibi to ti n kọ ọpẹ ninu oko naa, lo ba yinbọn fun wọn. Loootọ, o ti sọ fun baba mi pe ki wọn ma denu oko naa mọ, amọ baba mi ko ka ọrọ rẹ kun, nitori oko baba wọn ni, awọn mejeeji ni wọn si lẹtọọ si ogun rẹ.
“Ọkunrin ọdẹ kan lo gburoo ibọn ti aburo baba mi yin, lo ba sare lọ sibẹ lati wo o boya ọkan ninu wọn lo pa ẹran. Nigba ti ọdẹ naa debẹ, inu rẹ dun nigba to ri Ekapong pẹlu apo tẹjẹ wa lara ẹ yanmọyanmọ, o ro pe ẹran nla kan lọkunrin naa pa.
Si iyalẹnu rẹ, nigba to tu apo naa wo, oku eeyan lo ba nibẹ, lo ba pariwo pe kawọn eeyan gba oun.
“Ohun tawọn eeyan ọhun ri ni bi ọkunrin to pa ẹgbọn ẹ yii, ṣe n ge ẹran ara ẹ bii ẹran maaluu, ni wọn ba fi ọrọ ọhun to ọlọpaa leti.’’
ALAROYE gbọ pe ọmọkunrin naa ti wa lakolo ọlọpaa, nibi to ti n ṣalaye ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Irene Ugbo, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin sọ pe loootọ niṣẹlẹ yii waye, bẹẹ lawọn si ti ri afurasi ọdaran naa mu, o si ti wa lakolo awọn bayii. O ni ni kete ti iwadii ba pari lawọn yoo foju rẹ bale-ẹjọ.