Ẹgbẹ Akọmọlede rọ ijọba: Ẹ sọ ẹkọ ede Yoruba di dandan lawọn ileewe

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọ Aje, Mande, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ yii, ni Aarẹ ẹgbẹ Akọmọlede ati aṣa Yoruba ilẹ Naijiria, Diakoni Ọmọwumi, sọ fun gbogbo awọn to peju sibi ipade apero wọn ọlọdọọdun tọdun 2023 yii, eyi to waye ni Ìbùdó Queen Elizabeth School, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, lo ti sọ pe ki gbogbo awọn alẹnu lọrọ, awọn ọba alaye nilẹ Yoruba, forikori, ki wọn ba awọn gomina ipinlẹ wọn sọrọ lori bi wọn yoo ṣe pọn ede Yoruba ni dandan lawọn ileewe gbogbo, paapaa ju lọ alakọọbẹrẹ, ki ede Yoruba ma baa di ede ẹru lawujọ.

Ibeere ti oludanilẹkọọ nibi eto naa, Ọmọwe Layọ Ogunlọla, lati Fasiti Ilọrin, n beere nibi ipade apero yii ni pe njẹ a ni ọba nilẹ Yoruba mọ bi? o ni nipinlẹ Kwara, ẹṣin la gbe lori a ti pa aṣa ti, to si n da awujọ ru, o ni awọn ọba alaye ko laṣẹ mọ, awọn gomina ti gba agbara lọwọ awọn ọba alaye, eyi lo mu ki aṣa Yoruba fẹẹ mẹ́ẹ́rí. O ni ohun to dun ni ju ni pe ede Yoruba ti awa ko kakun mọ ni wọn ti n kọ ni orile-ede Amẹrika bayii, ti awọn oyinbo si ti n kẹkọọ nipa ede ati aṣa ibilẹ Yoruba ni Fasiti Ibadan ati Fasiti Awolọwọ n’Ile-Ifẹ. Ogunlọla ni ohun to buru ju ni ka ya ede-elede tabi aṣa alaṣa, ka waa pa tiwa ti patapata, ẹya to ba si pa ede ati aṣa rẹ ti, afaimọ ki orile-ede rẹ ma parẹ lode agbaye.

Ni igunlẹ ọrọ rẹ, o ni ẹkọ nipa ede ati aṣa Yoruba ṣe pataki fun awọn ọmọ ileewe, bẹrẹ lati ileewe alakọọbẹrẹ titi de awọn ileewe giga gbogbo, tori pe ede abinibi ni ọmọ gbọ ju to le fi kẹkọọ akọ-yege.

Leave a Reply