Ọlawale Ajao, Ibadan
O da bii pe omi ti gbẹ lẹyin ẹja Oloye Adebayọ Adelabu, oludije funpo gomina lorukọ ẹgbẹ oṣelu Alatanpako, Accord Party, pẹlu bi awọn adari ẹgbẹ oṣelu ọhun ṣe deede ja a ju silẹ nigba ti idibo gomina ku ọjọ diẹ.
Ki i ṣe pe wọn kan kọ Pẹnkẹlẹmẹẹsi silẹ lasan, wọn ti ṣetan lati ṣiṣẹ ta ko o gan-an ni, wọn ni ẹgbẹ oṣelu Alaburada, People’s Democratic Party, lawọn yoo ṣiṣẹ fun ninu idibo gomina to n bọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidibnlogun, oṣu Kẹta yii, ki gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, le ṣe saa kan si i lori ijọba
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, Alaga ẹgbẹ oṣelu Akọọdu nipinlẹ Ọyọ, Ọmọọba Kọlade Ojo, sọ pe awọn ti pada lẹyin Adelabu, nitori awọn ko nigbagbọ olookan bayii ninu ẹ.
Gẹgẹ bi Ọmọọba Kọlade ṣe sọ, “Lẹyin idibo aarẹ to kọja lawa oloye ẹgbẹ Akọọdu nipinlẹ Ọyọ ati gbogbo awọn alaga ẹgbẹ yii nijọba ibilẹ mẹtẹẹtalelọgbọn (33) to wa nipinlẹ yii ṣepade, ta a si pinnu pe ohun to daa ju ni ka pin gaari pẹlu oludije fun ipo gomina lorukọ ẹgbẹ wa, nitori ko si ibaṣepọ gidi kan laarin awa pẹlu ẹ.
“Akiyesi ta a ṣe ni pe iwọnba awọn to tẹle Adelabu wa lati inu ẹgbẹ to ti waa dara pọ mọ Akọọdu nikan lo fẹran lati maa ba ṣe, o kan fẹẹ lo awa ta a ti wa ninu ẹgbẹ yii tẹlẹ lasan ni, o si maa pada pa wa ti nigbẹyin.
“Oloye Adebayọ Adelabu ko ni ọwọ ati apọnle rara fan awa ta a jẹ adari ẹgbẹ yii. Nitori idi eyi la ṣe mọ pe Adelabu ko yẹ lẹni ta a le ṣatilẹyin fun lati de aaye nla bii ipo gomina ipinlẹ Ọyọ”.
Amọ ṣaa, awọn adari ẹgbẹ oṣelu Alatanpako ti sọ pe loootọ lawọn ti pada lẹyin Adelabu to n dupo gomina lorukọ ẹgbẹ naa, igbesẹ awọn yii ko di awọn to n dupo aṣofin ipinlẹ Ọyọ lorukọ ẹgbẹ oṣelu naa lọwọ lati kopa ninu idije naa, ki wọn si wọle idibo naa lọjọ Satide to n bọ.