Ọlawale Ajao Ibadan
Lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ti yan alaga apapọ wọn lai dibo, ti wọn si ti dibo yan awọn alaga ipinlẹ gbogbo fẹgbẹ naa ṣaaju, igbagbọ Aarẹ orileede yii,
Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari atawọn adari ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ni pe igbesẹ yii yoo mu iṣọkan ba ẹgbẹ oṣelu naa, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ ni ipinlẹ Ọyọ nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọhun kan ti dibo yan alaga mi-in.
Lọwọlọwọ bayii, ọga meji lo wa ninu ọkọ iṣakoso ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ bayii ti wọn n lọ ṣiarin ọkọ iṣakoso ẹgbẹ naa mọra wọn lọwọ.
Lọjọ Abamẹta, Satide, ọgbọnjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021, ni wọn dibo yan kọmiṣanna fọrọ ilẹ nipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Ọnarebu Ajiboye Ọmọdewu ni wọn kọkọ dibo yan sipo alaga Ẹgbẹ APC.
Bo tilẹ jẹ pe ikunsinu wa laarin awọn agba ẹgbẹ naa lori iyansipo Ọmọdewu, idibo gbogbogbo lati yan alaga atawọn alakooso apapọ ẹgbẹ naa ni igbagbọ ti kọkọ wa pe yoo mu alaafia jọba ninu ẹgbẹ naa, ṣugbọn bi wọn ṣe yan Sẹnetọ Abdullahi Adamu gẹgẹ bii alaga apapọ ẹgbẹ APC l’Ọjọbọ, Tọsidee, bo ṣe daaarọ Furaidee lawọn kan ninu ẹgbẹ oṣelu yii nipinlẹ Ọyọ kora wọn jọ, ti wọn si yan Abu Gbadamọsi gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ ọhun mi-in.
Ninu ọgba Trans Amusement Park, to wa laduugbo Bodija, n’Ibadan, ni wọn ti bura fọkunrin naa pẹlu awọn igbimọ ti wọn yoo jọ maa ṣe jọba.
Awọn to n gbero lati dupo gomina lorukọ ẹgbẹ naa lasiko idibo ọdun 2023 la gbọ pe wọn wa nidii iyapa to wa ninu ẹgbẹ oṣelu yii.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ọkan ninu awọn to fẹẹ dupo gomina yii, Sẹnetọ Tẹslim Fọlarin, ẹni to n ṣoju ẹkun idibo Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin agba nilẹ yii lo n ṣatilẹyin fun Ọmọdewu.
Nitori ki Sẹnetọ naa ma baa ri ẹgbẹ gba mọ wọn lọwọ fun anfaani ara rẹ lasiko idibo ti wọn yoo fi yan oludije fun ipo gomina lorukọ ẹgbẹ naa lawọn eeyan Oloye Adegoke Adelabu Pẹnkẹlẹmẹẹsi, ti oun naa fẹẹ ṣe gomina, ṣe lọọ yan awọn oloye mi-in laaye ara wọn.