Ẹgbẹ APC Rivers ko ni i ni oludije kankan feto idibo 2023

Faith Adebọla

Ohun to ṣẹlẹ si ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, nipinlẹ Rivers, lọdun 2019, eyi ti ko jẹ ki wọn le kopa ninu eto idibo gbogbogboo ọdun naa ti tun wa sojutaye lasiko yii pẹlu bi ile-ejọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Port Harcourt, olu-ilu ipinlẹ naa, ṣe wọgi le eto idibo abẹle ti wọn fi yan awọn oludije ti yoo kopa ninu eto idibo gbogbogbo tọdun 2023 ninu ẹgbẹ naa. Bakan naa ni wọn wọgi le gbogbo oludije ti wọn yan, wọn ni ojooro ati aidọgba foju han ninu eto idibo abẹle wọn, ko si bofin mu rara.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, nidajọ naa waye ninu ẹjọ kan ti Alagba George Orlu, atawọn mẹrin mi-in tinu n bi ninu ẹgbẹ naa pe ta ko eto idibo abẹle wọn ọhun.

Awọn olupẹjọ yii rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ ki wọn wọgi le eto idibo abẹle naa, wọn lọmọ ẹgbẹ APC lawọn, awọn ni kaadi ọmọ-ẹgbẹ awọn lọwọ, awọn si ti n ba ẹgbẹ naa bọ tipẹ, awọn gba fọọmu lati dije fun awọn ipo kan, ṣugbọn niṣe ni ẹgbẹ naa kan gba owo awọn sapo, wọn o jẹ kawọn kopa ninu eto idibo abẹle naa, wọn yọ orukọ awọn danu bii ẹni yọ jiga, wọn o tiẹ jẹ kawọn raaye wọle sibi ti wọn ti n ṣeto idibo.

Awọn olupẹjọ naa ni ki i ṣe awọn nikan ni ẹgbẹ APC Rivers huwa aidaa yii si o, wọn lọpọ eeyan ni ẹgbẹ naa tilẹkun ẹtọ wọn mọ, ti wọn si fi ọwọ ọla gba awọn loju.

Lẹyin atotonu olupẹjọ ati awijare olujẹjọ, Onidaajọ E. A. Obile ni ẹri ti ko ṣee jiyan le lori wa niwaju ile-ẹjọ naa pe awọn ọmọ-ẹgbẹ gidi lawọn olupẹjọ wọnyi, ati pe APC ta fọọmu idije fun wọn. Adajọ ni iwa ojooro ati ifẹtọ-ẹni-du-ni lo jẹ lati gbegi dina fawọn eeyan naa lasiko idibo abẹle, tori iwa to ta ko ofin eto idibo tọdun 2022 ni, bẹẹ lo ta ko ofin orileede wa paapaa.

Latari eyi, ile-ẹjọ paṣẹ pe gbogbo eto idibo naa, ati awọn oludije ti wọn yan nibẹ, irọ n purọ fun irọ ni, wọn wọgi le gbogbo wọn. Wọn ni niwọn igba ti ẹgbẹ APC Rivers ko ti tẹle ilana ofin eto idibo, gbogbo igboke-gbodo ati igbesẹ ti wọn fi yan oludije ko rẹsẹ walẹ labẹ ofin, wọn si paṣẹ fun ajọ eleto idibo, INEC, lati pa orukọ gbogbo awọn oludije ti wọn yan naa rẹ kia mọsa.

Ile-ẹjọ naa ko fun wọn lanfaani lati ṣeto idibo abẹle mi-in, leyii to tumọ si pe ẹgbẹ APC ipinlẹ Rivers ko ni oludije kankan ti yoo fa kalẹ fun ipo eyikeyii lọdun 2023, ayafi bi wọn ba pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, tabi ti idajọ to ga ju mi-in ba waye.

Amọ ṣa o, Alukoro apapọ fẹgbẹ APC, Darlington Nwaujun, ti fi atẹjade kan lede lori iṣẹlẹ yii, o ni ọgbọnkọgbọn lawọn kan ti wọn mori mu sibi kan n da lati ri i pe ẹgbẹ APC ipinlẹ Rivers ko ni i kopa ninu eto idibo 2023, o ni iromi wọn to n jo labẹ omi, awọn ti wa onilu ẹ to wa nisalẹ odo kan, tori idajọ ti ko le gbeṣẹ ni idajọ yii, awọn si maa pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun laipẹ, lati fẹ idajọ naa danu bii elubọ.

O ni ile-ẹjọ giga ju lọ ilẹ wa ti ṣedajọ nigba kan pe ọrọ abẹle ẹgbẹ ti ko kan ẹnikẹni lọrọ eto idibo abẹle, bo ba si ṣe wu awọn oloye ẹgbẹ ni wọn le ṣeto idibo abẹle wọn, tori ẹlẹnu rirun lo ni amu iya rẹ, ko seyii to kan ile-ẹjọ atawọn olupẹjọ ti wọn n paara ile-ẹjọ wọnyi, o lawọn maa gba idajọ mi-in to yatọ laipẹ, o si rọ awọn ọmọ-ẹgbẹ APC Rivers lati lọọ fọkan ara wọn balẹ, ki wọn si duro ti ẹgbẹ bo ṣe yẹ.

Leave a Reply