Ẹgbẹ awọn adajọ orileede yii da meji ninu wọn duro lẹnu iṣẹ

 Adewale Adeoye

Ni bayii, ẹgbẹ awọn adajọ lorileede yii, ‘National Judicial Council’ (NJC) labẹ iṣakoso olori wọn tuntun, iyẹn Onidaajọ Kudirat Ọlatokunbọ Kekere-Ẹkun, ti fiya nla jẹ awọn adajọ agba marun-un kan nitori ti wọn jẹbi awọn ẹsun iwa palapala ati iwa ibajẹ ti wọn fi kan wọn.

Nibi ipade pataki ẹgbẹ naa kan to waye laipẹ yii ni wọn ti kede irufẹ ijiya nla ti wọn fi jẹ awọn adajọ agba ọhun.

ALAROYE gbọ pe ipade ẹgbẹ naa kan to maa n waye lọdọọdun, iru rẹ  tọdun yii to waye lọjọ kẹtala si ọjọ kẹrinla, oṣu yii, ni wọn ti da adajọ agba tile-ẹjọ giga kan to wa niluu Rivers, iyẹn Adajọ G.C Aguma lẹbi lori bi ko ṣe tẹle ilana ofin to rọ mọ iṣẹ rẹ lasiko to n gbọ ẹjọ kan ti wọn gbe wa siwaju rẹ.

Ẹjọ to ṣakoba fun un yii waye ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2020. Wọn lọwọ yọbọkẹ lo fi mu ẹjọ gidi naa, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ rara. Fun idi eyi, wọn da a duro lẹnu iṣẹ rẹ fun ọdun kan gbako lai ni i gbowo oṣu lọwọ ijọba. Bakan naa ni wọn yoo maa foju ṣunukun wo iṣẹ rẹ fọdun meji gbako lẹyin to ba pada sẹnu iṣẹ rẹ.

Irufẹ ijiya nla yii kan naa ni wọn da fun adajọ agba ile-ẹjọ giga kan niluu Anambra, Onidaajọ O.A Nwabunike. Wọn da oun naa duro lẹnu iṣẹ rẹ fun ọdun kan gbako lai ni i gbowo oṣu lọwọ ijọba. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe ko tẹle ofin to rọ mọ iṣẹ rẹ lasiko to n ṣe idajọ ẹjo kan ti wọn gbe wa siwaju rẹ.

Yatọ sawọn adajọ agba mejeeji wọnyi ti wọn da duro lẹnu iṣẹ, wọn tun kan an nipa fawọn adajọ agba meji kan pe ki awọn naa lọọ kọwe fiṣẹ wọn silẹ ni kia, nitori ti wọn paro ọjọ ori wọn lẹnu iṣẹ.

Wọn rọ gomina ipinlẹ Imo, pe ko gbaṣẹ lọwọ Adajọ agba, Onidaajọ T.E Chukwuemeka Chikeka, ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o paro ọjọ ori rẹ. Wọn ni bẹrẹ lati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lo gbọdọ fiṣẹ silẹ, nitori iye ọdun to yẹ ko lo nidii iṣẹ ijọba ti kọja. Bakan naa ni wọn sọ fun un pe ko da owo-oṣu ọdun meji, bẹrẹ lati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2021, si asiko yii, to ti gba lọwọ ijọba pada loju-ẹsẹ.

Iwe ẹri ọjọọbi oriṣii meji lo wa ninu faili rẹ akọkọ, nibi to ti sọ pe ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 1956, ni wọn ti bi oun. Iwe ẹri ọjọọbi keji sọ pe ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 1958. Wọn ni iwadii ti awọn ṣe fi han gbangba pe iwe-ẹri ọjọọbi ti akọkọ lo jẹ gidi, o si tun lo iwe-ẹri ọjọọbi keji naa lati fi sun ọjọ to yẹ ko fiṣẹ silẹ siwaju si i fun ọdun meji, to si ti gbowo oṣu lọwọ ijọba.

Ẹṣẹ kan naa ni Onarebu Kadi Mahdi ṣẹ, oun naa parọ ọjọ ori rẹ ni. Iwe ẹri ọjọọbi akọkọ toun naa fi silẹ sọ pe ọjọ kẹwaa, oṣu, Kejila, ọdun 1958, ni wọn bi i, nigba tiwee ẹri ọjọọbi keji sọ pe ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 1959 ni. Ṣugbọn nigba nigba ti wọn maa ṣewadii nipa iwe-ẹri ọjọọbi rẹ, ọdun 1952 ni wọn bi i. Igbimọ alabẹ ṣekele to ṣewadi nipa iṣẹlẹ ọhun rọ awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa pe ki wọn ni ko lọọ kọwe fiṣẹ silẹ ni kia. Bakan naa ni wọn sọ pe ko da owo ọdun mejila to ti gba lọwọ ijọba pada loju-ẹsẹ.

Wọn rọ gomina ipinlẹ Yobe pe ko gbaṣẹ lọwọ rẹ ni kia.

Bakan naa ni wọn kilọ gidi gan-an fun Adajọ agba, Onidaajọ I.A Jamil, tipinlẹ Kogi, lori bo ṣe n ṣe amulo ofin. Wọn ni ki i ṣe ọwọ yẹpẹrẹ lo yẹ ko maa fi mu awọn ẹjọ to lewu.

Leave a Reply