Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Alaga ẹgbẹ awọn dokita ati agbẹbi nilẹ yii, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Dokita Saka Agboola, ti kede pe awọn ti fopin si iyanṣẹlodi ọnikilọ ọlọjọ meje ti ẹgbẹ naa ti kede rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii.
Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni alaga ọhun kede pe ẹgbẹ naa ti ṣẹwe-le iyanṣẹlodi naa, bẹrẹ lati aago mẹfa irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja, lẹyin ipade pajawiri kan ti ẹgbẹ naa ṣe pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni ẹgbẹ awọn dokita lawọn ileewosan ijọba nipinlẹ Kwara gun le iyanṣẹlodi ọlọjọ meje lati fi kilọ fun ijọba lori amojuto igbaye-gbadun wọn.
Dokita Agboola ni awọn pinnu lati fopin si iyanṣẹlodi ọhun lẹyin ifikunlukun pẹlu ijọba. Bakan naa lo ki awọn alaisan ku afarada inira ti wọn dojukọ lasiko iyanṣẹlodi naa.