Ọrẹoluwa Adedeji
‘’A ki i ni ọkọ nilẹ ka maa fi ọwọ ko igbọnsẹ, ba a ba n pese epo wa funra wa lorileede yii, airiṣẹ ṣe yoo dinku, ọwọ awọn eeyan ko ni i ma dilẹ, bẹẹ ni yoo din iwa ọdaran ku, ti yoo si le fun wa ni anfaani ati igboya lati le ka ara wa kun ọkan lara awọn orileede ti wọn n ta epo si Oke-Okun, iyẹn Organization of Petroleum Exporting Countries (OPEC)’’.
Eyi ni ọrọ ti ẹgbẹ awọn gomina nilẹ wa sọ nipasẹ Alaga wọn, to jẹ Gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma, lori bi orileede Naijiria ṣe tun n lọọ fọ epo ti a n lo nilẹ wa wa lati ilẹ okeere, bo tilẹ jẹ pe Naijiria naa wa ninu ẹgbẹ awọn orileede ti wọn ma ta epo s’Oke-Okun. O sọ eleyii di mimọ fawọn oniroyin lasiko ipade awọn gomina to waye niluu Abuja, eyi to ti bẹrẹ lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹwaa, to ṣẹṣẹ pari yii.
Nibi ipade naa ni wọn ti pe ọga agba patapata fun ileeṣẹ to n mojuto ọrọ epo bẹntiroolu nilẹ wa, Ọgbẹni Mele Kyari, lati waa sọ igbesẹ ti wọn ti n gbe lati ri i pe epo wa lọpọ yanturu fawọn araalu lari ra ni owo ti ko ga ni lara.
Nibẹ ni awọn gomina yii ti fẹnuko pe o ṣe pataki lati tẹle aṣẹ ti Aarẹ orileede yii, Bọla Tinubu, pa nipa ṣiṣe koriya fun ileeṣe ifọpo Dangote, ki wọn si tun awọn ileeṣẹ ifọpo to wa ni Portharcourt, Warri ati Kaduna ṣe ko le maa ṣiṣe. Wọn ni ki i ṣe ohun to bojumu lati maa mu owo ile lọ sita, ati pe o ṣe pataki lati maa pese ohun ti a ba n jẹ, ka si maa jẹ ohun ti a ba pese. Eleyii to ni yoo mu ki awọn eeyan riṣẹ ṣe, ko si ni i jẹ ki ọwọ awọn eeyan dilẹ, nitori ọwọ to ba dilẹ ni eṣu n bẹ niṣẹ. Bẹẹ ni yoo tun mu idagbasoke ba ọrọ-aje orileede yiim ti owo ilẹ wa yoo si tun lagbara si i gẹgẹ bi awọn gomina naa ṣe sọ.
Uzodima ni, ‘’Loju temi o, ki i ṣe ohun to bojumu, ohun itiju gbaa ni pẹlu, pe orileede wa gbara le ki a maa lọọ fọ epo ti a fẹẹ lo ni ilẹ Okeere, nigba ti awa paapaa wa ninu ẹgbẹ awọn orileede ti wọn n ta epo si ilẹ Okeere. Rira epo bẹntiroolu ni owo Naira lo le ṣanfaani fun wa, bẹẹ ni ka maa pese rẹ funra wa lorileede wa lo le mu nnkan rọrun fun wa. Bakan naa ni yoo mu anfaani to pọ wa fun awọn eeyan orileede yii, ti yoo si tun mu ki ọrọ aje ilẹ wa rugọgọ si i.
Ẹgbẹ awọn gomina yii ni awọn mọ loootọ loootọ pe orileede yii n koju iṣoro lọwọ yii, ṣugbọn awọn ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu Aarẹ Tinubu lati mu ohun gbogbo pada bọ sipo.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii, ni Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ifọpo Dangote, Alaaji Aliko Dangote, sọ nibi ipade awọn igbimọ kan to ni i ṣe pẹlu epo rọbi, eyi ti Aarẹ Tinubu ati ọga ileeṣẹ to n mojuto ọrọ epo bẹntiroolu nilẹ wa, (NNPCL), Ọgbẹni Mele Kyari naa wa pe ileeṣẹ oun ti ni epo to le kari gbogbo ohun ti awọn ọmọ Naijiria nilo lati lo nilẹ. O ni lita epo bẹntiroolu bii miliọnu lọna ọgbọn ni ileesẹ naa n pese lojumọ, lai si idiwọ kankan. Bakan naa lo ni awọn ni ẹẹdẹgbẹta miliọnu lita epo bẹntiroolu ti awọn ti ṣe silẹ nipamọ, leyii to jẹ pe bi ko ba si epo nibikibi tabi ti ohunkohun ba ṣẹlẹ, awọn ọmọ Naijiria yoo maa ri epo lo fun odidi ọjọ mejila lai si wahala kankan.
Lasiko naa ni Dangote rọ ileesẹ NNPCL pe ki wọn yee wa ohun to wa ninu ṣokoto wọn lọ si Ṣokoto pẹlu bi wọn ṣe ni awọn n reti epo bẹntiroolu bii lita mọkanlelogun lati Oke-Okun. O ni igbesẹ ti wọn n gbe naa yoo mu ki epo ma wa ni arọwọto awọn araalu, ti yoo si ko inira ba wọn.
Ọpọ eeyan lo ti n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti ileeṣẹ NNPCL n gbe yii, wọn ni bii ifowoṣofo ati nina owo ile sita ni bi wọn ṣe tun n gbe epo ti a maa lo lọ si ilẹ okeere lati fọ, nigba ti ileeṣẹ ifọpo kan ti wa nilẹ to ti n ṣiṣẹ, ti anfaani si tun wa fun wọn lati tun awọn eyi to bajẹ kaakiri orileede wa ṣe.