Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni ẹgbẹ kan ti wọn n pe ara wọn ni Higher Nigeria Movement (HNM) ẹka tipinlẹ Kwara, ṣe ipolongo alaafia niluu Ilọrin, ti wọn si n pe fun ki Igbakeji Aarẹ nilẹ yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, dupo aarẹ lọdun 2023, tori pe oun lo yẹ loye.
Ṣe ni gbogbo oju popo kun fọfọ lowurọ kutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, nigba ti ọgọọrọ awọn obinrin ati awọn ọdọ gbe oniruuru akọle lọwọ niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, ti wọn si n kọ oniruuru orin lati fi ṣe atilẹyin fun Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, wọn ni o ti ṣe gudugudu meje ati yaaya mẹfa, o ti pitu meje tawọn ọdẹ maa n pa nigbo gẹgẹ bii Igbakeji Aarẹ, to si ti mu ilọsiwaju ati idagbasoke ba eto ọrọ aje orile-ede yii, fun idi eyi, oun gan-an ni wọn fẹ ko maa tukọ Naijiria lọ lati ọdun 2023, to ri pe o kun oju oṣuwọn.
Adari ẹgbẹ naa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Bamgboye Lekan, ṣalaye fawọn oniroyin pe Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti ko ipa manigbagbe nipa gbigbe agbara wọ awọn obinrin ati awọn ọdọ lorile-ede yii, to si ti ni aṣeyọri nipa mimu idagbasoke ba eto ọrọ-aje ilẹ wa, to si gbe awọn eto lọkan-o-jọkan kalẹ ti Naijiria fi kapa arun Korona. Fun idi eyi, Ọṣinbajo nikan lo tẹwọn ti yoo tukọ orile-ede yii de ebute ogo.
Lara awọn to darapọ mọ ẹgbẹ yii ni awọn ọdọ to jẹ oniruuru ẹya, awọn iyalọja ati awọn oniṣẹ ọwọ, ti wọn si n pariwo, ‘Yẹmi Ọṣinbajo’ la fẹ gẹgẹ bii aarẹ lọdun 2023.