Jọkẹ Amọri
Ẹgbẹ kan to n ri si atilẹyin bi Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo yoo ṣe wọle fun ipo aarẹ Naijiria lasiko idibo ọdun to n bọ, Ọṣinbajo Grassroots Organisation (OGO), ti ṣe atilẹyin fun Igbakeji Aarẹ naa pẹlu miliọnu mẹẹẹdogun Naira lati fi gba fọọmu ẹgbẹ APC, eyi ti wọn fẹẹ ta fun awọn oludije ni miliọnu lọna ọgọrun-un Naira.
Ẹni to n ṣe kokaari ẹgbẹ naa, Foluṣọ Ojo, ṣalaye pe ida mejidinlọgọrun-un awọn ti wọn da owo naa jọ jẹ awọn eeyan ti wọn da a keekeeke, to si jẹ pe ẹni to da owo to kere si ẹgbẹrun marun-un wa ninu wọn.
O fi kun un pe awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun marun-un ti wọn gbagbọ ninu Ọṣinbajo pe yoo mu ayipada ba orileede yii, ti yoo si ri i pe aparo kan ko ga ju ọkan lọ, ti yoo fi otitọ ati inu ọkan sin orileede yii lo da owo ọhun jọ, awọn ko si ni i ja wọn kulẹ rara.
Ọ tẹsiwaju pe laarin ọjọ marun-un pere lawọn fi tu owo naa jọ, eyi to fi igbagbọ awọn eeyan ninu Ọṣinbajo han.
Ẹgbẹ ọhun ti wọn le ni miliọnu kan aabọ ti wọn wa kaakiri wọọdu to din diẹ ni ẹgbẹrun mẹsan-an kaakiri Naijiria ṣeleri pe awọn yoo ko awọn eeyan bii miliọnu lọna ogun ti yoo fi ibo wọn ṣatilẹyin fun Ọṣinbajo lẹyin ti wọn ba yan an gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ APC lọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, lati dupo aarẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ẹgbẹ kan to n ṣatilẹyin fun Ọjọgbọn Ọṣinbajo kan naa ti kọkọ da ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira ti wọn laọn fi ṣatilẹyin fun ọkunrin naa lati gba fọọmu idije sipo aarẹ ninu oṣu Kẹta, ọdun yii.