Ẹgbẹ Labour fa Peter Obi kalẹ funpo aarẹ 2023

Faith Adebọla

Gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ, Peter Obi, ni yoo dije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, ninu eto idibo gbogbogboo to n bọ ni 2023.
Eyi waye latari bi ọkunrin naa ṣe jawe olubori ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu ọhun lọjọ Aje, Mọnde, ọgbọnjọ, oṣu Karun-un yii.
Ilu Asaba ni apero apapọ ẹgbẹ Labour ti waye, nibi ti awọn aṣoju ẹgbẹ naa ti ṣeto idibo lati yan ẹni ti yoo dije dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn.
Awọn oludije mẹta ọtọọtọ ni wọn ba Peter Obi dije fun iyansipo naa, orukọ wọn ni Ọjọgbọn Pat Utomi, Olubusọla Emmanuel-Tella ati Joseph Fadurin.
Ko ti i ju ọsẹ kan sẹyin lọ ti Peter Obi kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, nibi to ti gba fọọmu ogoji miliọnu Naira lati dije fun ipo aarẹ, ṣugbọn ti ko le tẹsiwaju ninu erongba rẹ ọhun mọ. Ọjọ kẹta lẹyin naa lo lọọ darapọ mọ ẹgbẹ Labour Party yii.
Ọjọ Satide to kọja ni PDP ṣeto idibo abẹle wọn, ti wọn si dibo yan Alaaji Atiku Abubakar gẹgẹ bii oludije fun ipo aarẹ wọn. Bẹẹ ni tawọn APC yoo waye ni ọjọ kẹfa si ikeje, oṣu Kẹfa.
Tẹ o ba gbagbe, Peter Obi ni oludije fun igbakeji aarẹ pẹlu Atiku Abubakar ninu eto idibo gbogbogboo tọdun 2019, ṣugbọn ifa ko fọre fun wọn.

Leave a Reply