Jọkẹ Amọri
Ẹgbẹ oṣelu Labour ti ke si ajọ eleto idibo ilẹ wa pe ki wọn dawọ ikede esi idibo ti wọn n ṣe lọwọ duro loju-ẹsẹ. Eyi ko sẹyin bi ẹgbẹ naa ṣe sọ pe wọn kọ lati lo ọna ti aabo to dara fi le wa fun eto idibo, iyẹn maṣinni ti wọn fi n ṣe akọsilẹ iye awọn to dibo ti wọn n pe ni BVAS.
Oludari eto ipolongo ibo fun Obi, Akin Ọṣuntokun lo sọrọ naa fawọn oniroyin niluu Abuja. O ni ẹgbẹ oṣelu Labour ko ni igbẹkẹle ninu eto ibo kika ọhun. O waa ke si awọn ajọ agbaye lati ba wọn foju lameyitọ wo awọn iwa ati igbesẹ ti ajọ eleto idibo n gbe lori esi idibo ọdun 2023 yii.
Ọṣuntokun ni, ‘‘A n fi asiko yii ke si ajọ eleto idibo pe ki wọn dawọ ikede esi idibo duro, ki wọn si tẹle alakalẹ ti wọn fi lelẹ lori ibo didi, tabi ki wọn wọgi le gbogbo esi idibo naa, ki wọn si ṣeto idbo mi-in pẹlu alakalẹ ti ofin sọ lori eto idibo.
‘‘O ba wa ninu jẹ lati kede pe a ko nigbagbọ ninu esi idibo ti wọn n gbe jade. A waa ke si ajọ agbaye ki wọn mu ileri ti wọn ṣe lori eto idibo yii ṣẹ nipa dida si awọn iwa ibi ti awọn aṣaaju wa kan n hu, nitori pe ilana to wa fun gbogbo ajọ agbaye naa lo gbọdọ wa fun Naijiria, ko gbọdọ yatọ’’.
Ẹgbẹ Labour ni pẹlu bi ajọ eleto idibo ko ṣe tẹle gbogbo awọn ileri ti wọn ṣe lori eto idibo yii ti ti jẹ ki eto idibo naa ma poju owo.
Oṣuntokun ni funra ajọ eleto idibo ni wọn wa si gbangba, ti wọn si ṣeleri pe awọn yoo ṣe eto idibo to poju owo, bẹẹ ni wọn ni awọn ti mura silẹ ni digbi fun eto idbo naa, ṣugbọn gbogbo ohun to n ti ẹyin idibo yii yọ ko fi han pe wọn wa ni imurasilẹ rara.
O bu ẹnu atẹ lu INEC atawọn ẹṣọ alaabo ti wọn fọwọ sowọpọ lati yi ifẹ inu awọn araalu pada. O ni oriṣiiriṣii fidio to gba ori ayelujara to n fi iwa ibajẹ, iwa jagidijagan ati ifọwọsowọpọ ajọ eleto idibo lati ṣeru ba ni lọkan jẹ gidigidi.