Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Agbarijọ ẹgbẹ oṣere onitiata ni Naijiria ta a mọ si Nollywood, ti fi ẹbun miliọnu mẹrin naira ta awọn ọmọ Oloogbe Racheal Oniga to jẹ ọkan lara wọn lọrẹ gẹgẹ bii owo iranwọ lẹyin iku obinrin naa.
Ọmọọba Jide Kosọkọ ati Kate Henshaw toun maa n ṣere oloyinbo ni wọn ṣoju ẹgbẹ oṣere Naijiria pata nibi eto igboroyin fun oloogbe naa to waye lopin ọsẹ.
Awọn ni ẹgbẹ fi sọwedowo onimiliọnu mẹrin naa ran sawọn ọmọ Racheal, wọn si fi i jiṣẹ loju gbogbo awọn to wa nibẹ, wọn mu un fun ọkan ninu awọn ọmọ ti Racheal fi saye lọ.
Bẹ o ba gbagbe, ọgbọnjọ, oṣu keje, ni oṣere tiata ọmọ ipinlẹ Delta to maa n ṣere Yoruba daadaa naa jade laye lẹni ọdun mẹrinlelọgọta (64), awọn ẹbi rẹ si kede pe ọjọ kẹrindinlọgbọn ati ikẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ yii, ni eto isinku rẹ yoo waye.