Ẹgbẹ oṣelu APC lo wọle gbogbo idibo ijọba ibilẹ ipinlẹ Ogun 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ, All Progressives Congress (APC), lo jawe olubori ninu gbogbo ipo oṣelu ti wọn tori ẹ dibo ijọba ibilẹ to waye nipinlẹ Ogun.

Loru mọju ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlogun (17), oṣu Kọkanla yii, lajọ eleto idibo ipinlẹ Ogun, iyẹn, Ogun State Independent Electoral Commission, (OGSIEC), kede esi idibo ijọba ibilẹ to waye kaakiri ipinlẹ naa lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindilogun (16), oṣu yii.

Ijọba ibilẹ ogun (20) lo wa nipinlẹ Ogun, eeyan ogun naa lo si gbe apoti ibo lati di alaga kansu. Wọọdu mẹrindinlọọọdunrun (296) lo wa kaakiri awọn ijọba ibilẹ naa, ti apapọ awọn eeyan to dupo kansilọ wọọdu kọọkan si jẹ mẹrindinlọọọdunrun bo tilẹ jẹ pe wọn ti yinbọn pa ọkan ninu wọn lọjọ idibo ku ọla.

Ẹgbẹ oṣelu mọkandinlogun (19) lo du awọn ipo alaga kansu ati kansilọ naa. Ṣugbọn ati ipo alaga kansu, ati ti kansilọ ti wọn dibo yan lọjọ Satide ọhun, kikida ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni gbogbo wọn patapata.

Nigba to n ka awọn abajade idibo naa lolu ileeṣẹ ajọ naa to wa l’Oke-Ilewo, niluu Abẹokuta, Alaga ajọ OGSIEC, Ọgbẹni Babatunde Ọṣibodu, sọ pe ibo to le diẹ lẹgbẹrun lọna ẹgbẹta (613,516) lapapọ ibo ti awọn oludibo di ni ijọba ibilẹ ogun (20) to wa nipinlẹ ọhun.

Amọ ṣa, ẹgbẹ oṣelu Labour Party, ti fi aidunnu wọn han si esi idibo naa. Wọn ko ti i pari ibo didibo rara ti awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu ọhun ti ba awọn oniroyin sọrọ, wọn ni awọn ko fara mọ bi eto idibo ọhun ṣe n lọ, nitori kikidaa aparutu ati magomago lo kun inu ẹ bamubamu.

Awọn ẹgbẹ oṣelu mọkọọkandinlogun (19) to kopa ninu idibo naa ni APC, People’s Democratic Party (PDP), Accord Party (AP), African Action Congress (AAC), African Democratic Congress (ADC), Action Democratic Party (ADP), Allied People’s Movement (APM) ati All Progressives Grand Alliance (APGA).

Awọn yooku ni Labour Party (LP), Social Democratic Party (SDP), Young Progressive Party (YPP), Action People’s Party (APP), Action Alliance (AA), Boot Party (BP), People’s Redemption Party (PRP), National Rescue Movement (NRM), ati Zenith Labour Party (ZLP).

Leave a Reply