Ọlawale Ajao, Ibadan
Pẹlu bi awuyewuye ṣe n lọ kaakiri pe Igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan,f n mura lati fi ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), silẹ lọọ dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu alatako nipinlẹ ọhun. Igbakeji gomina naa ti fìdi ẹ mulẹ pe ẹgbẹ oṣelu marun-un ọtọọtọ lo n ba oun sọrọ lati waa dupo lorukọ ẹgbẹ wọn.
Nigba to n sọrọ yii fakọroyin ede Oyinbo kan lọfiisi ẹ l’Agodi, n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee. Ẹnjinnia Ọlaniyan fidi ẹ mulẹ siwaju pe mẹrin ninu awọn ẹgbẹ oṣelu ọhun ni wọn n fi tikẹẹti ipo gomina lọ oun lorukọ ẹgbẹ wọn.
O ni nilẹ toni to mọ yii, ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ṣi loun. Ṣugbọn Ọlọrun nikan lo mọ ebute ti ọkọ oun yoo gunlẹ si ninu irinajo oun nidii oṣelu.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹgbẹ oṣelu marun-un ọtọọtọ lo n fi tikẹẹti lọ mi lati waa dupo lorukọ ẹgbẹ wọn. Mẹrin ninu wọn lo n fipo gomina lọ mi.
Mo ti ni ipa ninu ọpọlọpọ ẹgbẹ oṣelu sẹyin. Mo jẹ ọkan ninu awọn to da ẹgbẹ ADC silẹ. Gbogbo wọn ni wọn n fi tikẹẹti lọ mi ṣugbọn mo ni ki wọn ni suuru fun mi digba ti Ọlọrun maa tọ mi sọna. Ipo gomina ki i ṣe nnkan ti mi o le ṣe.
“Mo le ma lowo lọwọ, ṣugbọn mo ni nnkan meji, mo ni ọmọluabi, mo si lawọn eeyan rere to jẹ ọmọluabi lẹyin rẹpẹtẹ. Nilẹ Yoruba si ree, a pataki ọmọluabi ju owo lọ.
“Mi o sọ pe mo ti fi ẹgbẹ PDP silẹ o. Mi o ti i dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu kankan, ọmọ ẹgbẹ PDP naa ṣi ni mi. Ṣugbọn idi ti awọn eeyan ṣe ri i pe mi o da si ọrọ ẹgbẹ ni pe emi ki i da si nnkan ti wọn o ba pe mi si.”
Sent from Yahoo Mail on Android