Ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party (NNPP), nipinlẹ Ọṣun, ti sọ pe ki Gomina Ademọla Adeleke maa palẹ ẹru rẹ mọ nile ijọba, nitori ọdun 2026 lopin iṣejọba rẹ.
Lasiko ti wọn n ṣi awọn sẹkiteriati ẹgbẹ naa ni Aarin Gbungbun ipinlẹ Ọṣun, ni alaga wọn, Dokita Tosin Ọdẹyẹmi, sọ pe ẹgbẹ PDP ti ja awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ni tanmọ-ọn. O
ṣalaye pe awọn iṣẹ akanṣe ti ko ni ipa taara lori igbesi aye awọn araalu nijọba Gomina Adeleke n ṣe, o si buru jai pe ṣe lawọn olowo n lowo si i, ti awọn talaka si n talaka si i.
O ni ẹgbẹ NNPP ti ṣetan, wọn ti wa kaakiri ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun, wọn si ti n la awọn araalu lọyẹ nipa idi ti wọn fi gbọdọ dibo fun ẹgbẹ oṣelu ti yoo bu omi itura sibi ti bata ti n ta wọn lẹsẹ lọdun 2026.
O sọ siwaju pe bi awọn ṣe n mura nijọba ibilẹ, lawọn ko duro rara nipinlẹ, bẹẹ naa si ni ọrọ yoo ri lorileede yii lọdun 2027, nitori ẹgbẹ NNPP yoo ṣi Aarẹ Bọla Tinubu nidii.
O ke si awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati farada iwọnba asiko diẹ to ku fun ẹgbẹ PDP, ki wọn si ni ipinnu ọkan lati mu ki ẹgbẹ naa lulẹ lọdun 2026.
Amọ ṣa, Alakooso iroyin fun ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun, Oladele Bamiji, sọ pe ẹgbẹ oṣelu NNPP ko ni agbara lati da atunyansipo Gomina Adeleke duro rara.
O ni gbogbo nnkan tawọn araalu n sọ kaakiri fi han pe gomina ti wọn nifẹ si ni Adeleke, gbogbo nnkan to n ṣe lo n ba wọn lara mu, bẹẹ lo ni akoyawọ ninu iṣejọba rẹ.