Jọkẹ Amọri
Lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, ni ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe ayẹwo fun awọn oludije wọn bii mẹtadinlogun, ti wọn si wọgi le awọn meji ninu wọn pe wọn ko kun oju oṣuwọn lati dije dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn.
Bo tilẹ jẹ pe awọn mejeeji yii ni wọn san miliọnu lọna ọgọrin Naira ti wọn ta fọọmu naa, ko jọ pe ẹgbẹ yii ṣetan lati da owo wọn pada, bi wọn yoo ba tiẹ waa da a pada gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ kan ṣe yọ sọ fun ALAROYE, ki i ṣe gbogbo owo naa ni awọn ti wọn ja bọ latari pe wọn ko kun oju oṣuwọn yii maa ri gba.
Ni nnkan bii aago meje alẹ ti wọn pari eto ayẹwo naa ni Alaga igbimọ to n ṣe ayẹwo fun awọn to fẹẹ dije naa, Sẹnetọ David Mark, sọ eleyii di mimọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko darukọ awọn ti wọn wọgi le orukọ wọn yii.
O kan ni awọn eeyan naa ko kun oju oṣuwọn ni awon fi wọgi le orukọ wọn. O fi kun un pe awọn yoo gbe esi ayẹwo tawọn ṣe naa ranṣẹ si Igbimọ Amuṣẹya ẹgbẹ naa fun igbesẹ to ba yẹ.