Ẹgbẹ oṣiṣẹ binu s’awọn gomina: Ki ẹni ti ko ba le sanwo-oṣu tuntun tete kuro nipo

Faith Adebọla

Lọgbọ-lọgbọ to n ṣẹlẹ latari owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lọ, eyi ti ẹgbẹ awọn gomina ilẹ wa ni awọn ko lagbara lati san ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira (N60,000) tijọba apapọ fi lọ awọn oṣiṣẹ ti gbọna mi-in yọ, ọrọ ọhun si ti fa isọko ọrọ sira ẹni, pẹlu bi ẹgbẹ oṣiṣẹ, Nigeria Labour Congress (NLC), ṣe gboju àgan sawọn gomina, wọn ni ki gomina to ba ri i pe oun ko lagbara lati san iyekiye tawọn ba fẹnu ko si tete kuro lori aleefa, wọn ni ki tọhun kọwe fipo silẹ lai jafara ni.

Igbakeji Alaga apapọ fun ẹgbẹ awọn ọlọja, Trade Union Congress (TUC), Ọgbẹni Tommy Etim, lo kọkọ sọrọ yii laṣaalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ta a wa yii, niluu Abuja.

Etim ni, “Ko si ohun to n jẹ owo-oṣu to kere ju (minimum wage), tori owo to le mu keeyan wa laaye (living wage) la n ja fun, gbogbo ohun ta a ba ṣi fẹnu ko le lori lo gbọdọ di ṣiṣe.

“Ni tọrọ awọn gomina yẹn, a o yọ ọ sọ o. Ẹni ti ko ba le san owo-oṣu to kere ju, ko jọwọ, kọwe fipo silẹ ni, ki i ṣe tori ati pese nnkan amayedẹrun nìkan laraalu ṣe dibo yan yin, tori kẹ ẹ le ṣejọba ni.

“Bẹ ẹ ba ṣe ohun amayedẹrun mere-mere to pọ, amọ ti araalu tẹ ẹ tori ẹ ṣe e ti ku tan, ta lo fẹẹ lo o?

“Nigba ti wọn n polongo ibo, ti wọn n ṣe kampeeni kiri, ṣe wọn sọ fun wa pe awọn ko ni i le sanwo-oṣu ni? Wọn o sọ iyẹn fun wa. Wọn lo awọn mẹkunnu lati de’po, wọn de’bẹ tan, ironu wọn ti yatọ.

“Ṣebi ni orileede yii kan naa t’awọn gomina ti n sọ pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn pọ ju agbara wọn lọ, ibẹ naa ni gomina kan ti ko obitibiti owo, biliọnu mọkandinlaaadọrun-un (N89b) jẹ, to waa n sa kiri. Abẹ o ri ara! Awa ẹgbẹ oṣiṣẹ maa sepade. A n fun Aarẹ Tinubu ni anfaani boya o maa ṣe bo ṣe wi ni. Ohun to ba ṣẹlẹ lo maa sọ igbesẹ ta a maa gbe,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Bakan naa ni Alukoro fun ẹgbẹ NLC, Ọgbẹni Benson Upah, ti fesi lori ọrọ tawọn gomina sọ ọhun.

Upah ni, “A gbagbọ pe ero ti ko daa lo mu k’awọn gomina sọ ohun ti wọn sọ yẹn. Ko ṣee gbọ seti pe ọrọ ko ti i pari, idunaa-dura ṣi n lọ lọwọ, awọn ti n sare gbe iru ọrọ bẹẹ yẹn sita faye gbọ. Ọrọ ti ko dùn lẹnu ni wọn n sọ.

Ẹ jẹ ka wo o boya ootọ wa ninu ọrọ wọn, owo tijọba apapọ n pin fawọn ipinlẹ loṣooṣu, iyẹn alokeṣan, ti lọ soke latori ẹẹdẹgbẹrin biliọnu (N700bn) si tiriliọnu kan o le (N1.2tn) bayii, eyi to mu kijọba lowo bii ṣẹkẹrẹ, taraalu si n laalaṣi.

“Ko sohun t’awọn gomina yii ni lati ṣe ki wọn baa le sanwo-oṣu to kere ju lọ ju pe ki wọn dín owo inakunaa ti wọn fi n ṣejọba ku, ki wọn din ikowojẹ ku, ki wọn si mú igbaye-gbadun awọn oṣiṣẹ ni gbogi. Tori awa o tiẹ ti i gba ọgọta ẹgbẹrun ti wọn n pariwo ẹ yii wọle o”.

Bẹẹ l’agbẹnusọ NLC naa sọ.

Leave a Reply