Ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn ko daṣẹ silẹ mọ

Adewale Adeoye

Lẹyin ipade oniwakati gbọọrọ kan to waye laarin aṣoju ijọba apapọ orileede yii atawọn aṣoju  ẹgbẹ oṣiṣẹ ilẹ wa, ‘Nigerian Labour Congress’ (NLC), pẹlu ajọ awọn oṣiṣẹ mi-in ti wọn n jẹ ‘Trade Union Congress’ (TUC), wọn ti fẹnuko pe ki awọn oṣiṣẹ gbogbo lorileede yii ma ṣe daṣẹ silẹ mọ gẹgẹ bii ipinu wọn tẹlẹ pe awọn bẹrẹ iyanṣẹlodi l’Ọjọruu, Wesidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.

Ẹni to kede iroyin ayọ ọhun fawọn ọmọ orileede yii ni Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, to tun jẹ olori awọn oṣiṣẹ ti wọn ṣẹṣẹ yan ninu ijọba to wa lode bayii, Ọnarebu Femi Gbajabiamiala.

Ipade ọhun to waye niluu Abuja, lọjọ Aje,  Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, la gbọ pe o gba aimọye wakati laarin awọn eeyan naa, nitori pe ko sẹni kan ninu wọn to fẹẹ gba gọjẹ rara fun ara wọn. Bawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣe n sọ pe awọn kò ni i fẹ, dandan ni ki  awọn daṣẹ silẹ ti wọn ko ba da owo epo bẹntiroolu pada si bo ti ṣe wa tẹlẹ ni kia, ni awọn ẹgbẹ ọlọja paapaa ko mu ọrọ ọhun ni kere rara, ti kaluku wọn si n sọ ẹdun ọkan wọn fawọn to wa nibẹ ti wọn n ṣoju ijọba apapọ nibi ipade ọhun.

Lopin ohun gbogbo, wọn fori ọrọ ọhun ti sibi kan, wọn si gba pe ki wọn fun awọn alaṣẹ ijọba apapọ ilẹ wa lọjọ bii meloo kan si i ki wọn fi sọhun ti wọn maa ṣe sọrọ owo-oṣu awọn oṣiṣẹ gbogbo lorileede yii, pẹlu bi wọn ṣe ṣafikun owo epo bẹntiroolu ilẹ wa lojiji.

Lẹyin ipade pataki naa ni Ọnarebu Gbajabiamila kede pe awọn aṣoju ijọba apapọ, ajọ oṣiṣẹ atawọn ajọ ọlọja yoo jokoo papọ ninu ipade kan ti yoo waye laipẹ yii, nibi ti wọn yoo ti jiroro lori ohun tijọba apapọ gbọdọ ṣe sọrọ owo-oṣu awọn oṣiṣẹ ilẹ wa.

Gbajabiamila ni, ‘Ohun ta a fẹnu ko le lori bayii ni pe kawọn aṣoju ajọ oṣiṣẹ nilẹ yii, atawọn ẹgbẹ awọn ọlọja naa mu awọn eeyan tiwọn wa, ta a si maa jọ jokoo papọ lati wa ojutuu sọrọ naa ni kia. Lara ohun ta a maa jọ sọrọ le lori ni iye ti wọn maa gba gẹgẹ bii owo-oṣu wọn, atawọn ohun kọọkan ti ijọba apapọ gbọdọ ṣe fun wọn lati jẹ ki igbe aye dẹrun fun wọn lẹyin ti wọn ti yọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa bayii.

Bẹ o ba gbagbe, gbara tijọba Tinubu kede rẹ pe oun ko ni i le sanwo iranwọ lori epo bẹntiroolu mọ ni awọn elépo ti fowo kun iye ti wọn n ta jala epo kan, bẹẹ ni gbogbo nnkan si gbowo lori ju bo ṣe yẹ lọ, eyi to mu aye nira fun awọn araalu.

Bi ki i naa ṣe ipade yii to da wọn lọwọ kọ, Wesidee, ọjọ keje, oṣu yii, ni wọn iba daṣẹ silẹ .

 

 

 


Leave a Reply