Monisọla Saka
Ẹgbẹ kan ti wọn pe ni ‘The Ọṣinbajo Think Tank’, iyẹn ẹgbẹ to n ṣatilẹyin fun Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ti ki ẹni to jawe olubori ninu ibo abẹle aarẹ inu ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ku oriire lẹyin to gbegba oroke lasiko eto idibo naa to waye niluu Abuja.
Awọn ẹgbẹ yii tun rọ aṣaaju gbogbogboo fẹgbẹ APC ọhun lati tun mu alekun ba iṣejọba rere nigba to ba depo aarẹ.
Ọgbẹni Olugbenga Ọlaoye to jẹ agbẹnusọ ẹgbẹ ọhun ni inu ẹgbẹ awọn dun si bi eto idibo abẹle naa ṣe lọ nirọwọ rọsẹ.
O sọ siwaju pe ẹgbẹ awọn, ni ibamu pẹlu afojusun awọn lati ṣe igbelarugẹ fun iṣejọba rere fi ọwọ ati gbogbo ara si gbogbo igbesẹ ijọba awa-ara-wa, gẹgẹ bi ẹgbẹ Onitẹsiwaju, iyẹn APC ṣe n ṣe.
O ṣapejuwe ijawe olubori Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu bii eyi to tọ si i ni tootọ, ti wọn ba ti ibi oniruuru idagbasoke to ti mu ba ijọba awa-ara-wa wo o.
Ọlaoye waa fi awọn eeyan ilẹ Naijiria lọkan balẹ pe iṣọkan Naijiria lo jẹ ẹgbẹ awọn logun, bẹẹ lo rọ gbogbo awọn to n gba a lero lati dupo oṣelu pe ki wọn tọpasẹ Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo.
O tun tẹsiwaju nipa sisọ ọrọ iwuri nipa aniyan rere ti Ọṣinbajo ni lọkan sorilẹ-ede yii, eyi to mu ko di aṣaaju laarin awọn to dupo aarẹ.
Ọlaoye waa ki Oṣinbajo funra ẹ ku oriire fun iwa olori pipe ati akin to hu, ni gbogbo igba ti wọn wa le e lọrun pe ko juwọ silẹ lasiko ibo abẹle naa.