Ẹgbẹ to n ṣatilẹyin fun Tinubu ṣewọde l’Abuja, wọn ni ko saaye ijọba fidi-hẹ

Adewale Adeoye

Awọn ẹgbẹ kan ti wọn pera wọn ni ‘Awọn ọmọ oniluu’ (The Natives)” ti sọ pe gbagbaagba bayii lawọn wa lẹyin aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lati di aarẹ ilẹ yii lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun-un, ọdun (29/5/2023) yii.  Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni wọn kora wọn jọ, ti wọn si ṣewọde wọọrọwọ kaakiri ilu Abuja, ti i ṣe olu ilu ilẹ wa Naijiria.

Koko iwọde ẹgbẹ ‘Awọn ọmọ Oniluu (The Natives)’ ọhun ni pe wọn n kilọ fawọn ẹgbẹ alatako gbogbo pẹlu awọn oloṣelu to dije dupo labẹ ẹgbẹ wọn gbogbo pe ki wọn yee fa wahala nla lẹsẹ rara nipa bi wọn ti ṣe n sọ pe ki Aarẹ Muhammadu Buhari gbejọba silẹ fun ijọba fidi-hẹ lẹyin to ba ti pari isakoso rẹ tan lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Ohun ti wọn n sọ ni pe, wọn ti dibo tan nilẹ yii, ẹni to si jawe olubori ti mọ ara rẹ bayii, ko tọna rara pe ki ẹgbẹ kan tabi oloṣelu kan waa maa ro pe boun ko ṣe lanfaani lati wọle yẹn, ki wọn doju ohun gbogbo bolẹ lo ku.

‘Awọn ọmọ Oniluu (The Natives)’ ọhun sọ pe awọn ọlọpọlọ pipe kọọkan ti wọn jẹ ọmọ ilẹ yii ko ti i gbagbe rara bi awọn kan ṣe lo ọwọ agbara lati doju ibo to gbe Oloogbe MKO Abiọla wọle ni ‘June12’ lọdun 1993, ati pe ki wọn ma ṣe da a labaa rara lati tun gbe iru igbesẹ bẹẹ lakooko yii.

Awọn ti wọn ṣewọde kaakiri origun mẹrẹẹrin ilu Abuja ọhun sọ pe awọn fara mọ ọn pe ki alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, ṣi maa ba iṣẹ daadaa rẹ lọ, nitori pe o kunju oṣuwọn.

Ninu ọrọ olori ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Edward Smart, o rọ awọn alakooso ajọ agbaye gbogbo atawọn ọmọ orilẹ-ede yii pe ki wọn da sọrọ ohun ni kia, ki wọn ma ṣe jẹ ki eto iṣejọba dẹmokiresi ilẹ wa tun foriṣanpon laipe ọjọ.

Edward ni, “Ko sohun to jọ ọ pe wọn ja ẹtọ ẹnikankan gba rara, o ṣee ṣe ko jẹ pe bawọn oloṣelu alatako wọnyẹn ṣe kuna lati bori ninu ibo, wọn ko ṣiṣẹ daadaa to ni tabi pe awọn araalu ni ko nifẹẹ si ẹgbẹ wọn, tabi oloṣelu ti wọn fa kalẹ.

“ Akoko waa ree lati jẹ anfaani ijọba to daa gẹgẹ bii awọn ọmọ Oniluu (The Natives), akoko waa ree lati ri bi orileede wa Naijiria yoo ṣe ṣe daadaa niwaju awon ọlọtẹ gbogbo, akoko wa ree lati ri i pe ijọba dẹmokiresi ṣe daadaa, akoko wa ree lati ri bi ilẹ wa yoo ṣe maa nilọsiwaju si i ni gbogbo ọna bayii.”

“A n fi akoko yii sọ fun gbogbo awọn eeyan pe gbaagbaagba bayii la wa lẹyin aṣeyọri Tinubu, ati pe ko sohun to jọ pe a n ja ẹtọ ẹnikankan gba rara, ajọ IINEC ṣe daadaa lakooko idibo ọdun yii, eyi to mu ki ẹgbẹ NNPP bori nipinlẹ Kano, ti ẹgbẹ PDP paapaa si bori ni awọn ipinlẹ bii: Pọta, Enugu, Taraba, Delta, Plateau ati bẹẹ bẹẹ lọ. Bẹẹ ni ọmọ ẹgbẹ APC to dije dupo ọhun nipinlẹ Plateau paapaa ti ki ẹni to bori ku oriire bayii, ati pe ẹni ti ko ba tẹ lọrun, ko gba kootu lọ.

Nipa awọn ẹgbẹ kan ti wọn ṣewọde kaakiri laipẹ yii, ti wọn si n sọ pe ki wọn gbejọba fun ijọba fidi-hẹ, Smart sọ pe ki i ṣohun  to daa rara lati maa beere fun iru nnkan bẹẹ, nigba ti ẹni ti ajọ INEC kede rẹ wa nilẹ.

Ni kukuru, ẹgbẹ Awọn ọmọ Oniluu (The Natives) lawọn ko fara mọ ọn rara pe ki Aarẹ Buhari gbejọba kalẹ fun ijọba fidi-hẹ kankan, paapaa ju lọ nigba ti ajọ INEC ti kede rẹ pe Tinubu lo wọle sipo naa bayii.

O waa rọ awọn alakooso ijọba agbaye gbogbo lati tete gbe igbesẹ pataki lori ọrọ to n lọ naa, ki wọn si pana ogun pẹlu ọtẹ ọhun ni kia, nitori pe orilẹ-ede wa Naijiria wa lara awọn ibujokoo irọrun wọn nigba gbogbo, ko si ni i da rara bi wọn ba laju wọn silẹ ki wọn jẹ ki awọn ọlọtẹ ba ohun gbogbo jẹ pata ko too di pe wọn gbe igbesẹ.

“Mo rọ gbogbo ẹya kọọkan patapata, yala wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ APC tabi PDP, tabi ẹgbẹ yoowu ti ibaa jẹ pe ki wọn fọwọ wọnu, ki wọn ṣe suuru sohun gbogbo, ki wọn si jẹ kogun o mi bayii, nitori ohun to le ṣe gbogbo araalu lanfaani niyẹn’’.

Lọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun yii, gan-an ni yoo pe ọgbọn ọdun gbako ti wọn ṣe eru nla fun Oloogbe MKO ti ko fi lanfaani lati depo pataki ti o n le nigba naa lọhun-un, awọn ologun to doju ohun gbogbo ru lakooko naa ni wọn tun pada gbe agbada wọ sọrun bayii, ti wọn si fẹẹ mu awọn ileri wọn ṣẹ poo.

Leave a Reply