Jọkẹ Amọri
Bo tilẹjẹ pe ko ti i sọ iru ijiya ti wọn maa fun un, Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Sẹnetọ Abdullahi Adamu, ti sọ pe awọn yoo fiya jẹ oludije dupo aarẹ labẹ ẹgbẹ naa, Aṣiwaju Bọla Tinubu, lori awọn ọrọ ti wọn lo sọ si Aarẹ Buhari lasiko to ṣabẹwo si awọn aṣoju ẹgbẹ naa ti yoo kopa ninu ibo abẹle lati yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ wọn ninu idibo ọdun to n bọ.
Adamu sọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nile ẹgbẹ naa niluu Abuja. O ni bo tilẹ jẹ pe agba oloṣelu naa ti tọrọ aforiji, sibẹ, ọrọ to sọ niwaju awọn aṣoju ati ọpọ eeyan to wa nibẹ jẹ ọrọ arifin ati ifiniwọlẹ eyi ti ẹgbẹ yoo si fiya jẹ ẹ lori rẹ.
Tẹ o ba gbagbe, lasiko ti Tinubu n rọ awọn aṣoju ẹgbẹ naa lati dibo fun un lo sọ pe oun loun ṣatilẹyin fun Aarẹ Buhari lọdun 2014 to fi depo aarẹ.
O ni ẹẹmeta ọtọọtọ ni Buhari gbiyanju lati di aarẹ, ṣugbọn ti ko ṣee ṣe ko too di pe oun ṣatilẹyin fun un, to si pada rọwọ mu.